Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 3:32-38 BIBELI MIMỌ (BM)

32. Heburoni ni wọ́n sin òkú Abineri sí, ọba sọkún létí ibojì rẹ̀, gbogbo àwọn eniyan sì sọkún pẹlu.

33. Dafidi kọ orin arò kan fún Abineri báyìí pé:“Kí ló dé tí Abineri fi kú bí aṣiwèrè?

34. Wọn kò dì ọ́ lọ́wọ́,bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dì ọ́ lẹ́sẹ̀;o ṣubú bí ìgbà tí eniyan ṣubú níwájú ìkà.”Gbogbo eniyan sì tún bú sẹ́kún.

35. Gbogbo eniyan rọ Dafidi, pé kí ó jẹun ní ọ̀sán ọjọ́ náà ṣugbọn ó búra pé kí Ọlọrun pa òun bí òun bá fi ẹnu kan nǹkankan títí tí ilẹ̀ yóo fi ṣú.

36. Gbogbo àwọn eniyan ṣe akiyesi ohun tí ọba ṣe yìí, ó sì dùn mọ́ wọn. Gbogbo ohun tí ọba ṣe patapata ni ó dùn mọ́ àwọn eniyan.

37. Gbogbo àwọn eniyan Dafidi, ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ni ó hàn sí gbangba pé, ọba kò lọ́wọ́ ninu pípa tí wọ́n pa Abineri.

38. Ọba bi àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ṣé ẹ kò mọ̀ pé eniyan ńlá, ati alágbára kan ni ó ṣubú lónìí, ní ilẹ̀ Israẹli?”

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 3