Dafidi pàṣẹ pé kí Joabu ati àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ fa aṣọ wọn ya, kí wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀, kí wọ́n sì ṣọ̀fọ̀ Abineri. Nígbà tí ó tó àkókò láti sìnkú Abineri, Dafidi ọba pàápàá tẹ̀lé òkú rẹ̀.