Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 3:29-39 BIBELI MIMỌ (BM)

29. Orí Joabu ati ìdílé baba rẹ̀ ni ẹ̀bi ìjìyà ikú yìí yóo dà lé. Láti ìrandíran rẹ̀, kò ní sí ẹnikẹ́ni tí kò ní kó àtọ̀sí, tabi kí ó ní àrùn ẹ̀tẹ̀, tabi tí kò ní jẹ́ pé iṣẹ́ obinrin nìkan ni wọn yóo lè ṣe, tabi kí wọ́n pa wọ́n lójú ogun, tabi kí wọ́n máa tọrọ jẹ.”

30. Bẹ́ẹ̀ ni Joabu ati Abiṣai, arakunrin rẹ̀, ṣe pa Abineri tí wọ́n sì gbẹ̀san ikú Asaheli, arakunrin wọn, tí Abineri pa lójú ogun Gibeoni.

31. Dafidi pàṣẹ pé kí Joabu ati àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ fa aṣọ wọn ya, kí wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀, kí wọ́n sì ṣọ̀fọ̀ Abineri. Nígbà tí ó tó àkókò láti sìnkú Abineri, Dafidi ọba pàápàá tẹ̀lé òkú rẹ̀.

32. Heburoni ni wọ́n sin òkú Abineri sí, ọba sọkún létí ibojì rẹ̀, gbogbo àwọn eniyan sì sọkún pẹlu.

33. Dafidi kọ orin arò kan fún Abineri báyìí pé:“Kí ló dé tí Abineri fi kú bí aṣiwèrè?

34. Wọn kò dì ọ́ lọ́wọ́,bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dì ọ́ lẹ́sẹ̀;o ṣubú bí ìgbà tí eniyan ṣubú níwájú ìkà.”Gbogbo eniyan sì tún bú sẹ́kún.

35. Gbogbo eniyan rọ Dafidi, pé kí ó jẹun ní ọ̀sán ọjọ́ náà ṣugbọn ó búra pé kí Ọlọrun pa òun bí òun bá fi ẹnu kan nǹkankan títí tí ilẹ̀ yóo fi ṣú.

36. Gbogbo àwọn eniyan ṣe akiyesi ohun tí ọba ṣe yìí, ó sì dùn mọ́ wọn. Gbogbo ohun tí ọba ṣe patapata ni ó dùn mọ́ àwọn eniyan.

37. Gbogbo àwọn eniyan Dafidi, ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ni ó hàn sí gbangba pé, ọba kò lọ́wọ́ ninu pípa tí wọ́n pa Abineri.

38. Ọba bi àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ṣé ẹ kò mọ̀ pé eniyan ńlá, ati alágbára kan ni ó ṣubú lónìí, ní ilẹ̀ Israẹli?”

39. Ó ní, “Agbára mi dínkù lónìí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òróró ni a fi yàn mí ní ọba. Ìwà ipá àwọn ọmọ Seruaya yìí ti le jù fún mi. OLUWA nìkan ni ó lè san ẹ̀san fún eniyan burúkú gẹ́gẹ́ bí ìwà ìkà rẹ̀.”

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 3