Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 3:24-34 BIBELI MIMỌ (BM)

24. Joabu bá lọ sí ọ̀dọ̀ ọba, ó bèèrè pé, “Irú kí ni o ṣe yìí, Abineri wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, o sì jẹ́ kí ó lọ bẹ́ẹ̀?

25. Ṣebí o mọ̀ pé ó wá tàn ọ́ jẹ ni? Ó wá fi ọgbọ́n wádìí gbogbo ibi tí ò ń lọ, ati gbogbo ohun tí ò ń ṣe ni.”

26. Nígbà tí Joabu kúrò lọ́dọ̀ Dafidi, ó ranṣẹ lọ pe Abineri, wọ́n sì dá a pada láti ibi kànga Sira, ṣugbọn Dafidi kò mọ nǹkankan nípa rẹ̀.

27. Nígbà tí Abineri pada dé Heburoni, Joabu mú un lọ sí kọ̀rọ̀ kan, níbi ẹnubodè, bí ẹni pé ó fẹ́ bá a sọ ọ̀rọ̀ àṣírí, Joabu bá fi nǹkan gún un ní ikùn. Bẹ́ẹ̀ ni Abineri ṣe kú, nítorí pé ó pa Asaheli arakunrin Joabu.

28. Nígbà tí Dafidi gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó ní, “OLUWA mọ̀ pé, èmi ati àwọn eniyan mi kò lọ́wọ́ sí ikú Abineri rárá, ọwọ́ wa mọ́ patapata ninu ọ̀ràn náà.

29. Orí Joabu ati ìdílé baba rẹ̀ ni ẹ̀bi ìjìyà ikú yìí yóo dà lé. Láti ìrandíran rẹ̀, kò ní sí ẹnikẹ́ni tí kò ní kó àtọ̀sí, tabi kí ó ní àrùn ẹ̀tẹ̀, tabi tí kò ní jẹ́ pé iṣẹ́ obinrin nìkan ni wọn yóo lè ṣe, tabi kí wọ́n pa wọ́n lójú ogun, tabi kí wọ́n máa tọrọ jẹ.”

30. Bẹ́ẹ̀ ni Joabu ati Abiṣai, arakunrin rẹ̀, ṣe pa Abineri tí wọ́n sì gbẹ̀san ikú Asaheli, arakunrin wọn, tí Abineri pa lójú ogun Gibeoni.

31. Dafidi pàṣẹ pé kí Joabu ati àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ fa aṣọ wọn ya, kí wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀, kí wọ́n sì ṣọ̀fọ̀ Abineri. Nígbà tí ó tó àkókò láti sìnkú Abineri, Dafidi ọba pàápàá tẹ̀lé òkú rẹ̀.

32. Heburoni ni wọ́n sin òkú Abineri sí, ọba sọkún létí ibojì rẹ̀, gbogbo àwọn eniyan sì sọkún pẹlu.

33. Dafidi kọ orin arò kan fún Abineri báyìí pé:“Kí ló dé tí Abineri fi kú bí aṣiwèrè?

34. Wọn kò dì ọ́ lọ́wọ́,bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dì ọ́ lẹ́sẹ̀;o ṣubú bí ìgbà tí eniyan ṣubú níwájú ìkà.”Gbogbo eniyan sì tún bú sẹ́kún.

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 3