Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 3:11-21 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Iṣiboṣẹti kò sì lè dá Abineri lóhùn nítorí ó bẹ̀rù rẹ̀.

12. Abineri bá ranṣẹ sí Dafidi ní Heburoni pé, “Ṣebí ìwọ ni o ni ilẹ̀ yìí? Bá mi dá majẹmu, n óo wà lẹ́yìn rẹ, n óo sì mú kí gbogbo Israẹli pada sọ́dọ̀ rẹ.”

13. Dafidi bá dáhùn pé, “Ó dára, n óo bá ọ dá majẹmu. Ṣugbọn nǹkankan ni mo fẹ́ kí o ṣe, o kò ní fi ojú kàn mí, àfi bí o bá mú Mikali ọmọbinrin Saulu lọ́wọ́ nígbà tí o bá ń bọ̀ wá rí mi.”

14. Dafidi bá rán àwọn oníṣẹ́ kan sí Iṣiboṣẹti, ọmọ Saulu, pé kí ó dá Mikali, aya òun, tí òun san ọgọrun-un awọ orí adọ̀dọ́ àwọn ará Filistia lé lórí pada fún òun.

15. Iṣiboṣẹti bá ranṣẹ lọ gba Mikali lọ́wọ́ Palitieli, ọmọ Laiṣi, ọkọ rẹ̀.

16. Ṣugbọn bí ó ti ń lọ ni ọkọ rẹ̀ ń sọkún tẹ̀lé e títí tí ó fi dé Bahurimu, ibẹ̀ ni Abineri ti dá a pada, ó sì pada.

17. Abineri tọ àwọn àgbààgbà Israẹli lọ, ó ní, “Ó pẹ́ tí ẹ ti fẹ́ kí Dafidi jẹ́ ọba yín.

18. Àkókò nìyí láti ṣe ohun tí ẹ ti fẹ́ ṣe, nítorí pé OLUWA ti ṣe ìlérí fún Dafidi pé Dafidi ni òun óo lò láti gba àwọn ọmọ Israẹli kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Filistia ati gbogbo àwọn ọ̀tá wọn yòókù.”

19. Abineri bá àwọn ará Bẹnjamini sọ̀rọ̀ pẹlu. Lẹ́yìn náà ó lọ bá Dafidi ní Heburoni láti sọ ohun tí àwọn ará Bẹnjamini ati gbogbo ọmọ Israẹli ti gbà láti ṣe fún Dafidi.

20. Nígbà tí Abineri dé ọ̀dọ̀ Dafidi ní Heburoni pẹlu ogún ọkunrin tí ń bá a lọ, Dafidi se àsè ńlá fún wọn.

21. Abineri bá sọ fún Dafidi pé, “N óo lọ, n óo wá ọ̀nà tí gbogbo Israẹli yóo fi wà lẹ́yìn rẹ, oluwa mi, (ọba), tí wọn yóo bá ọ dá majẹmu tí o óo sì jọba lórí gbogbo ibi tí ọkàn rẹ bá fẹ́.” Dafidi ní kí ó máa lọ, ó sì lọ ní alaafia.

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 3