Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 3:1-17 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn ìdílé Saulu, ati àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn ìdílé Dafidi bá ara wọn jagun fún ìgbà pípẹ́. Bí agbára Dafidi ti ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ni agbára àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn Saulu ń dínkù.

2. Ọmọkunrin mẹfa ni wọ́n bí fún Dafidi nígbà tí ó wà ní Heburoni. Aminoni tí ìyá rẹ̀ ń jẹ́ Ahinoamu, ará Jesireeli, ni àkọ́bí.

3. Ekeji ni Kileabu, ọmọ Abigaili, opó Nabali, ará Kamẹli. Ẹkẹta ni Absalomu, ọmọ Maaka, ọmọ Talimai, ọba Geṣuri.

4. Ẹkẹrin ni Adonija ọmọ Hagiti. Ẹkarun-un ni Ṣefataya ọmọ Abitali.

5. Ẹkẹfa sì ni Itireamu, ọmọ Egila. Heburoni ni wọ́n ti bí àwọn ọmọ náà fún Dafidi.

6. Ní àkókò tí ogun wà láàrin àwọn eniyan Dafidi ati àwọn eniyan Saulu, agbára Abineri bẹ̀rẹ̀ sí pọ̀ sí i láàrin àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn Saulu.

7. Ní ọjọ́ kan, Iṣiboṣẹti ọmọ Saulu fi ẹ̀sùn kan Abineri pé ó bá obinrin Saulu kan, tí wọn ń pè ní Risipa, ọmọ Aya, lòpọ̀.

8. Ọ̀rọ̀ náà bí Abineri ninu gidigidi, ó bi Iṣiboṣẹti pé, “Ṣé o rò pé mo jẹ́ hu ìwà ọ̀dàlẹ̀ sí Saulu laelae? Àbí ẹ̀yìn àwọn ará Juda ni ẹ rò pé mo wà ni? Láti ìbẹ̀rẹ̀ ni mo ti jẹ́ olóòótọ́ sí Saulu baba rẹ, àwọn arakunrin rẹ̀ ati àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, èmi ni n kò sì ti jẹ́ kí apá Dafidi ká ọ. Ṣugbọn lónìí ńkọ́, ò ń fi ẹ̀sùn kàn mí nípa obinrin.

9. Kí Ọlọrun lù mí pa, bí n kò bá ṣe gbogbo ohun tí ó wà ní ìkáwọ́ mi, láti mú ìlérí tí OLUWA ṣe fún Dafidi ṣẹ,

10. pé, òun yóo gba ìjọba kúrò lọ́wọ́ ìdílé Saulu, yóo sì fi Dafidi jọba lórí Juda jákèjádò, láti Dani títí dé Beeriṣeba.”

11. Iṣiboṣẹti kò sì lè dá Abineri lóhùn nítorí ó bẹ̀rù rẹ̀.

12. Abineri bá ranṣẹ sí Dafidi ní Heburoni pé, “Ṣebí ìwọ ni o ni ilẹ̀ yìí? Bá mi dá majẹmu, n óo wà lẹ́yìn rẹ, n óo sì mú kí gbogbo Israẹli pada sọ́dọ̀ rẹ.”

13. Dafidi bá dáhùn pé, “Ó dára, n óo bá ọ dá majẹmu. Ṣugbọn nǹkankan ni mo fẹ́ kí o ṣe, o kò ní fi ojú kàn mí, àfi bí o bá mú Mikali ọmọbinrin Saulu lọ́wọ́ nígbà tí o bá ń bọ̀ wá rí mi.”

14. Dafidi bá rán àwọn oníṣẹ́ kan sí Iṣiboṣẹti, ọmọ Saulu, pé kí ó dá Mikali, aya òun, tí òun san ọgọrun-un awọ orí adọ̀dọ́ àwọn ará Filistia lé lórí pada fún òun.

15. Iṣiboṣẹti bá ranṣẹ lọ gba Mikali lọ́wọ́ Palitieli, ọmọ Laiṣi, ọkọ rẹ̀.

16. Ṣugbọn bí ó ti ń lọ ni ọkọ rẹ̀ ń sọkún tẹ̀lé e títí tí ó fi dé Bahurimu, ibẹ̀ ni Abineri ti dá a pada, ó sì pada.

17. Abineri tọ àwọn àgbààgbà Israẹli lọ, ó ní, “Ó pẹ́ tí ẹ ti fẹ́ kí Dafidi jẹ́ ọba yín.

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 3