Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 2:22-31 BIBELI MIMỌ (BM)

22. Abineri tún pe Asaheli, ó tún sọ fún un pé, “Pada lẹ́yìn mi, má jẹ́ kí n pa ọ́? Ojú wo ni o sì fẹ́ kí n fi wo Joabu ẹ̀gbọ́n rẹ?”

23. Ṣugbọn Asaheli kọ̀, kò pada. Abineri bá sọ ọ̀kọ̀ ní àsọsẹ́yìn, ọ̀kọ̀ sì lọ bá Asaheli ní ikùn, ọ̀kọ̀ náà sì yọ jáde lẹ́yìn rẹ̀. Asaheli wó lulẹ̀, ó sì kú síbi tí ó ṣubú sí. Gbogbo àwọn tí wọ́n bá ti dé ibi tí Asaheli kú sí, ni wọ́n ń dúró.

24. Ṣugbọn Joabu ati Abiṣai ń lé Abineri lọ, bí oòrùn ti ń lọ wọ̀, wọ́n dé ara òkè Ama tí ó wà níwájú Gia ní ọ̀nà aṣálẹ̀ Gibeoni.

25. Àwọn ọmọ ogun yòókù láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini kó ara wọn jọ sẹ́yìn Abineri, wọ́n sì dúró káàkiri lórí òkè, pẹlu ìmúra ogun.

26. Lẹ́yìn náà Abineri pe Joabu, ó ní, “Ṣé títí lae ni a óo máa ja ìjà yìí lọ ni? Àbí ìwọ náà kò rí i pé, bí a bá ja ogun yìí títí a fi pa ara wa tán, kò sí nǹkankan tí ẹnikẹ́ni yóo rí gbà, àfi ọ̀tá! Nígbà wo ni o fẹ́ dúró dà, kí o tó dá àwọn eniyan rẹ lẹ́kun pé kí wọ́n yé lépa àwọn arakunrin wọn?”

27. Joabu bá dáhùn pé, “Ọlọrun mọ̀, bí o bá dákẹ́ tí o kò sọ̀rọ̀ ni, àwọn eniyan mi kì bá máa le yín lọ títí di òwúrọ̀ ọ̀la.”

28. Joabu bá fọn fèrè ogun, láti fi pe àwọn eniyan rẹ̀ pada. Nígbà náà ni wọ́n tó pada lẹ́yìn àwọn eniyan Israẹli, tí wọ́n sì dáwọ́ ogun dúró.

29. Gbogbo òru ọjọ́ náà ni Abineri ati àwọn eniyan rẹ̀ fi ń rìn pada lọ ní àfonífojì Jọdani, wọ́n kọjá sí òdìkejì odò Jọdani. Gbogbo òwúrọ̀ ọjọ́ keji ni wọ́n sì fi rìn kí wọ́n tó pada dé Mahanaimu.

30. Nígbà tí Joabu pada lẹ́yìn Abineri, tí ó sì kó gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ jọ, ó rí i pé, lẹ́yìn Asaheli, àwọn mejidinlogun ni wọn kò rí mọ́.

31. Ṣugbọn àwọn eniyan Dafidi ti pa ọtalelọọdunrun (360) ninu àwọn eniyan Abineri.

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 2