Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 2:1-13 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Lẹ́yìn èyí, Dafidi bèèrè lọ́wọ́ OLUWA pé, “OLUWA, ṣé kí ń lọ sí ọ̀kan ninu àwọn ìlú Juda?”OLUWA sì dá a lóhùn pé, “Lọ.”Dafidi bá tún bèèrè pé, “Ìlú wo ni kí n lọ?”OLUWA ní, “Lọ sí ìlú Heburoni.”

2. Dafidi bá mú àwọn iyawo rẹ̀ mejeeji; Ahinoamu ará Jesireeli, ati Abigaili, opó Nabali, ará Kamẹli lọ́wọ́ lọ.

3. Ó kó àwọn ọkunrin tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ pẹlu, ati gbogbo ìdílé wọn, wọ́n sì ń gbé àwọn ìlú tí wọ́n wà ní agbègbè Heburoni.

4. Lẹ́yìn náà, àwọn ará Juda wá sí Heburoni, wọ́n fi òróró yan Dafidi ní ọba wọn. Nígbà tí Dafidi gbọ́ pé àwọn ará Jabeṣi Gileadi ni wọ́n sin òkú Saulu,

5. ó ranṣẹ sí wọn pé, “Kí OLUWA bukun yín nítorí pé ẹ ṣe olóòótọ́ sí Saulu ọba wa, ẹ sì sin òkú rẹ̀.

6. Kí OLUWA fi ìfẹ́ ńlá ati òdodo rẹ̀ hàn fun yín. Èmi náà yóo ṣe yín dáradára, nítorí ohun tí ẹ ṣe yìí.

7. Nítorí náà, ẹ mọ́kàn gírí kí ẹ sì ṣe akin; nítorí pé Saulu, oluwa yín ti kú, àwọn eniyan Juda sì ti fi òróró yàn mí gẹ́gẹ́ bí ọba wọn.”

8. Abineri ọmọ Neri, tíí ṣe balogun àwọn ọmọ ogun Saulu, gbé Iṣiboṣẹti ọmọ Saulu sá lọ sí Mahanaimu ní òdìkejì odò Jọdani.

9. Níbẹ̀ ni ó ti fi Iṣiboṣẹti jọba lórí gbogbo agbègbè Gileadi, Aṣuri, Jesireeli, Efuraimu, Bẹnjamini, ati lórí gbogbo ilẹ̀ Israẹli.

10. Ẹni ogoji ọdún ni nígbà tí wọ́n fi jọba lórí Israẹli, ó sì wà lórí oyè fún ọdún meji.Ṣugbọn ẹ̀yìn Dafidi ni gbogbo ẹ̀yà Juda wà.

11. Ọdún meje ààbọ̀ ni Dafidi fi jọba lórí ẹ̀yà Juda ní ìlú Heburoni.

12. Abineri ọmọ Neri ati àwọn iranṣẹ Iṣiboṣẹti, ọmọ Saulu, ṣígun láti Mahanaimu, lọ sí ìlú Gibeoni.

13. Joabu, tí orúkọ ìyá rẹ̀ ń jẹ́ Seruaya, ati àwọn iranṣẹ Dafidi yòókù lọ pàdé wọn níbi adágún Gibeoni. Àwọn tí wọ́n tẹ̀lé Joabu jókòó sí ẹ̀gbẹ́ kan adágún náà, àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn Abineri náà sì jókòó sí òdìkejì.

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 2