Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 11:17-25 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Àwọn ọmọ ogun àwọn ọ̀tá jáde láti inú ìlú láti bá àwọn ọmọ ogun Joabu jà. Wọ́n pa ninu àwọn ọ̀gágun Dafidi, wọ́n sì pa Uraya ará Hiti náà.

18. Joabu bá ranṣẹ sí Dafidi láti ròyìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lójú ogun fún un.

19. Ó sọ fún oníṣẹ́ tí ó rán pé, “Bí o bá ti sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lójú ogun fún ọba tán,

20. inú lè bí i, kí ó sì bèèrè lọ́wọ́ rẹ pé, ‘Kí ló dé tí ẹ fi súnmọ́ ìlú náà tóbẹ́ẹ̀ láti bá wọn jà? Ẹ ti gbàgbé pé wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí ta ọfà láti orí ògiri wọn ni?

21. Ẹ ti gbàgbé bí wọ́n ti ṣe pa Abimeleki ọmọ Gideoni? Ṣebí obinrin kan ni ó ju ọlọ ata sílẹ̀ láti orí ògiri ní Tebesi, tí ó sì pa á. Kí ló dé tí ẹ fi súnmọ́ ògiri tóbẹ́ẹ̀?’ Bí ọba bá bèèrè irú ìbéèrè yìí, sọ fún un pé, ‘Wọ́n ti pa Uraya, ọ̀kan ninu àwọn ọ̀gágun rẹ̀ pẹlu.’ ”

22. Oníṣẹ́ náà bá tọ Dafidi lọ, ó sì ròyìn fún un gẹ́gẹ́ bí Joabu ti rán an pé kí ó sọ.

23. Ó ní, “Àwọn ọ̀tá wa lágbára jù wá lọ, wọ́n sì jáde láti inú ìlú wọn láti bá wa jà ninu pápá, ṣugbọn a lé wọn pada títí dé ẹnubodè ìlú wọn.

24. Àwọn tafàtafà bẹ̀rẹ̀ sí ta ọfà sí wa láti orí ògiri wọn, wọ́n sì pa ninu àwọn ọ̀gágun rẹ, wọ́n pa Uraya náà pẹlu.”

25. Dafidi rán oníṣẹ́ náà sí Joabu pé, “Má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí da ọkàn rẹ rú níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé ẹnikẹ́ni kò lè mọ ẹni tí ogun yóo pa. Tún ara mú gidigidi, kí o sì gba ìlú náà.”

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 11