Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 10:11-17 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Joabu wí fún un pé, “Bí o bá rí i pé àwọn ará Siria fẹ́ ṣẹgun mi, wá ràn mí lọ́wọ́. Bí èmi náà bá sì rí i pé àwọn ará Amoni fẹ́ ṣẹgun rẹ, n óo wá ràn ọ́ lọ́wọ́.

12. Múra gírí, jẹ́ kí á fi gbogbo agbára wa jà fún àwọn eniyan wa ati fún ìlú Ọlọrun wa. Kí OLUWA wa ṣe èyí tí ó dára lójú rẹ̀.”

13. Joabu ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tẹ̀síwájú láti gbógun ti àwọn ará Siria, àwọn ará Siria sì sá.

14. Nígbà tí àwọn ará Amoni rí i pé àwọn ará Siria ń sá lọ, àwọn náà sá fún Abiṣai, wọ́n sì pada sinu ìlú. Joabu bá pada lẹ́yìn àwọn ará Amoni, ó sì lọ sí Jerusalẹmu.

15. Nígbà tí àwọn ará Siria rí i pé, àwọn ọmọ ogun Israẹli ti ṣẹgun àwọn, wọ́n kó gbogbo àwọn ọmọ ogun wọn jọ.

16. Hadadeseri ọba, bá ranṣẹ sí àwọn ará Siria tí wọ́n wà ní ìhà ìlà oòrùn odò Yufurate, wọ́n bá wá sí Helamu. Ṣobaki tí ó jẹ́ balogun àwọn ọmọ ogun Hadadeseri, ni aṣiwaju wọn.

17. Nígbà tí Dafidi gbọ́, ó kó gbogbo àwọn ọmọ ogun Israẹli jọ, ó la odò Jọdani kọjá lọ sí Helamu. Olukuluku àwọn ará Siria dúró ní ipò wọn, wọ́n dojú kọ Dafidi, wọ́n sì bá a jagun.

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 10