Nígbà tí àwọn ará Amoni rí i pé àwọn ará Siria ń sá lọ, àwọn náà sá fún Abiṣai, wọ́n sì pada sinu ìlú. Joabu bá pada lẹ́yìn àwọn ará Amoni, ó sì lọ sí Jerusalẹmu.