Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 1:9-22 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Saulu bá wí fún mi pé, ‘Sún mọ́ mi níhìn-ín, kí o pa mí, nítorí pé mo ti fara gbọgbẹ́, mò ń jẹ̀rora gidigidi, ṣugbọn ẹ̀mí mi ṣì wà sibẹ.’

10. Mo bá súnmọ́ Saulu, mo sì pa á. Nítorí mo mọ̀ pé, tí ó bá kúkú ṣubú lulẹ̀, yóo kú náà ni. Mo bá ṣí adé orí rẹ̀, mo sì bọ́ ẹ̀gbà ọrùn ọwọ́ rẹ̀. Àwọn ni mo kó wá fún ọ yìí, Dafidi, oluwa mi.”

11. Ni Dafidi ati gbogbo àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ bá fa aṣọ wọn ya láti fi ìbànújẹ́ wọn hàn.

12. Wọ́n ṣọ̀fọ̀, wọ́n sọkún, wọ́n sì gbààwẹ̀ títí di ìrọ̀lẹ́; nítorí Saulu ati Jonatani, ọmọ rẹ̀, ati àwọn ọmọ Israẹli, eniyan OLUWA nítorí pé ọpọlọpọ wọn ni wọ́n ti pa lójú ogun.

13. Dafidi bèèrè lọ́wọ́ ọdọmọkunrin tí ó wá ròyìn fún un pé, “Níbo ni o ti wá?”Ọdọmọkunrin náà dáhùn pé, “Ọmọ àlejò ará Amaleki kan, tí ń gbé ilẹ̀ Israẹli ni mí.”

14. Dafidi tún bi í pé, “Báwo ni ẹ̀rù kò ṣe bà ọ́ láti pa ọba, ẹni tí OLUWA fi àmì òróró yàn?”

15. Ni Dafidi bá pàṣẹ pé kí ọ̀kan ninu àwọn ọkunrin tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀, lọ pa ọdọmọkunrin ará Amaleki náà. Ọkunrin náà bá pa á.

16. Dafidi wí fún ọdọmọkunrin ará Amaleki náà pé, “Ìwọ ni o fa èyí sí orí ara rẹ. Ìwọ ni o dá ara rẹ lẹ́bi, nípa jíjẹ́wọ́ pé, ìwọ ni o pa ọba, ẹni tí OLUWA fi àmì òróró yàn.”

17. Dafidi bá kọ orin arò fún Saulu, ati Jonatani, ọmọ rẹ̀,

18. ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n kọ́ àwọn eniyan Juda ní orin náà. (Àkọsílẹ̀ rẹ̀ wà ninu Ìwé Jaṣari.) Orin arò náà lọ báyìí:

19. “A! Israẹli, wọ́n ti pa àwọn tí o fi ń ṣògo lórí àwọn òkè rẹ!Ẹ wo bí àwọn akikanju tí ń ṣubú!

20. Ẹ má ṣe sọ nípa rẹ̀ ní Gati,ẹ má ṣe ròyìn rẹ̀ ní ìgboro Aṣikeloni;kí inú àwọn obinrin Filistini má baà dùn,kí àwọn ọmọbinrin àwọn aláìkọlà má baà máa yọ̀.

21. “Ẹ̀yin òkè Giliboa,kí òjò má ṣe rọ̀ le yín lórí,bẹ́ẹ̀ ni kí ìrì má ṣe sẹ̀ sórí yín,kí èso kan má so mọ́ ní gbogbo orí òkè Giliboa,nítorí pé, ibẹ̀ ni apata àwọn akikanju ti dípẹtà;a kò sì fi òróró kun apata Saulu mọ́.

22. Ọrun Jonatani kì í pada lásán,bẹ́ẹ̀ ni idà Saulu kì í pada,láì fi ẹnu kan ẹ̀jẹ̀ àwọn tí ó pa,ati ọ̀rá àwọn akikanju.

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 1