orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40
  41. 41
  42. 42
  43. 43
  44. 44
  45. 45
  46. 46
  47. 47
  48. 48
  49. 49
  50. 50
  51. 51
  52. 52
  53. 53
  54. 54
  55. 55
  56. 56
  57. 57
  58. 58
  59. 59
  60. 60
  61. 61
  62. 62
  63. 63
  64. 64
  65. 65
  66. 66
  67. 67
  68. 68
  69. 69
  70. 70
  71. 71
  72. 72
  73. 73
  74. 74
  75. 75
  76. 76
  77. 77
  78. 78
  79. 79
  80. 80
  81. 81
  82. 82
  83. 83
  84. 84
  85. 85
  86. 86
  87. 87
  88. 88
  89. 89
  90. 90
  91. 91
  92. 92
  93. 93
  94. 94
  95. 95
  96. 96
  97. 97
  98. 98
  99. 99
  100. 100
  101. 101
  102. 102
  103. 103
  104. 104
  105. 105
  106. 106
  107. 107
  108. 108
  109. 109
  110. 110
  111. 111
  112. 112
  113. 113
  114. 114
  115. 115
  116. 116
  117. 117
  118. 118
  119. 119
  120. 120
  121. 121
  122. 122
  123. 123
  124. 124
  125. 125
  126. 126
  127. 127
  128. 128
  129. 129
  130. 130
  131. 131
  132. 132
  133. 133
  134. 134
  135. 135
  136. 136
  137. 137
  138. 138
  139. 139
  140. 140
  141. 141
  142. 142
  143. 143
  144. 144
  145. 145
  146. 146
  147. 147
  148. 148
  149. 149
  150. 150

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 84 BIBELI MIMỌ (BM)

Ṣíṣàárò Ilé Ọlọrun

1. Ibùgbé rẹ lẹ́wà pupọ, OLUWA àwọn ọmọ ogun,

2. ọkàn àgbàlá tẹmpili OLUWA ń fà mí,àárò rẹ̀ ń sọ mí;tọkàn-tara ni mo fi ń kọrin ayọ̀sí Ọlọrun alààyè.

3. Àwọn ẹyẹ ológoṣẹ́ pàápàá a máa kọ́ ilé,àwọn alápàáǹdẹ̀dẹ̀ a sì máa tẹ́ ìtẹ́níbi tí wọ́n ń pa ọmọ sí, lẹ́bàá pẹpẹ rẹ,àní lẹ́bàá pẹpẹ rẹ, OLUWA àwọn ọmọ ogun,ọba mi, ati Ọlọrun mi.

4. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń gbé inú ilé rẹ,wọn óo máa kọ orin ìyìn sí ọ títí lae!

5. Ayọ̀ ń bẹ fún gbogbo àwọn tí ó fi ọ́ ṣe agbára wọn,tí ìrìn àjò sí Sioni jẹ wọ́n lógún.

6. Bí wọ́n ti ń la àfonífojì Baka lọ,wọ́n ń sọ ọ́ di orísun omi;àkọ́rọ̀ òjò sì mú kí adágún omi kún ibẹ̀.

7. Wọn ó máa ní agbára kún agbára,títí wọn ó fi farahàn níwájú Ọlọrun ní Sioni.

8. OLUWA, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, gbọ́ adura mi;tẹ́tí sílẹ̀, Ọlọrun Jakọbu!

9. Bojú wo àpáta wa, Ọlọrun,fi ojú àánú wo ẹni àmì òróró rẹ.

10. Nítorí pé ọjọ́ kan péré ninu àgbàlá rẹ,ṣe anfaani ju ẹgbẹrun ọjọ́ níbòmíràn lọ.Ó wù mí kí n jẹ́ aṣọ́nà ninu ilé Ọlọrun miju pé kí n máa gbé inú àgọ́ àwọn eniyan burúkú.

11. Nítorí OLUWA Ọlọrun ni oòrùn ati ààbò wa,òun níí ṣeni lóore, tíí dáni lọ́lá,nítorí OLUWA kò ní rowọ́ láti fún ẹni tí ọkàn rẹ̀ mọ́ní ohun tí ó dára.

12. OLUWA àwọn ọmọ ogun,ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé ọ.