orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40
  41. 41
  42. 42
  43. 43
  44. 44
  45. 45
  46. 46
  47. 47
  48. 48
  49. 49
  50. 50
  51. 51
  52. 52
  53. 53
  54. 54
  55. 55
  56. 56
  57. 57
  58. 58
  59. 59
  60. 60
  61. 61
  62. 62
  63. 63
  64. 64
  65. 65
  66. 66
  67. 67
  68. 68
  69. 69
  70. 70
  71. 71
  72. 72
  73. 73
  74. 74
  75. 75
  76. 76
  77. 77
  78. 78
  79. 79
  80. 80
  81. 81
  82. 82
  83. 83
  84. 84
  85. 85
  86. 86
  87. 87
  88. 88
  89. 89
  90. 90
  91. 91
  92. 92
  93. 93
  94. 94
  95. 95
  96. 96
  97. 97
  98. 98
  99. 99
  100. 100
  101. 101
  102. 102
  103. 103
  104. 104
  105. 105
  106. 106
  107. 107
  108. 108
  109. 109
  110. 110
  111. 111
  112. 112
  113. 113
  114. 114
  115. 115
  116. 116
  117. 117
  118. 118
  119. 119
  120. 120
  121. 121
  122. 122
  123. 123
  124. 124
  125. 125
  126. 126
  127. 127
  128. 128
  129. 129
  130. 130
  131. 131
  132. 132
  133. 133
  134. 134
  135. 135
  136. 136
  137. 137
  138. 138
  139. 139
  140. 140
  141. 141
  142. 142
  143. 143
  144. 144
  145. 145
  146. 146
  147. 147
  148. 148
  149. 149
  150. 150

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 144 BIBELI MIMỌ (BM)

Ọpẹ́ fún Ìṣẹ́gun

1. Ìyìn ni fún OLUWA, àpáta mi,ẹni tí ó kọ́ mi ní ìjà jíjà,tí ó kọ́ mi ní iṣẹ́ ogun.

2. Òun ni àpáta mi, ààbò mi, odi mi, olùdáǹdè mi,asà mi, ẹni tí mo sá di.Òun ni ó tẹrí àwọn eniyan ba lábẹ́ rẹ̀.

3. OLUWA, kí ni eniyan jẹ́, tí o fi ń náání rẹ̀?Kí sì ni ọmọ eniyan tí o fi ń ranti rẹ̀?

4. Eniyan dàbí èémí,ọjọ́ ayé rẹ̀ sì dàbí òjìji tí ń kọjá lọ.

5. OLUWA, fa ojú ọ̀run wá sílẹ̀, kí o sì sọ̀kalẹ̀ wá,fọwọ́ kan àwọn òkè ńlá, kí wọ́n máa rú èéfín.

6. Jẹ́ kí mànàmáná kọ, kí o sì tú wọn ká,ta ọfà rẹ, kí o tú wọn ká.

7. Na ọwọ́ rẹ sílẹ̀ láti òkè,kí o yọ mí ninu ibú omi;kí o sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn àjèjì,

8. tí ẹnu wọn kún fún irọ́,tí ọwọ́ ọ̀tún wọn sì kún fún èké.

9. Ọlọrun, n óo kọ orin titun sí ọ,n óo fi hapu olókùn mẹ́wàá kọrin sí ọ.

10. Ìwọ ni ò ń fún àwọn ọba ní ìṣẹ́gun,tí o sì gba Dafidi, iranṣẹ rẹ, là.

11. Gbà mí lọ́wọ́ idà ìkà,gbà mí lọ́wọ́ àwọn àjèjì,tí ẹnu wọ́n kún fún irọ́,tí ọwọ́ ọ̀tún wọn sì kún fún èké.

12. Ní ìgbà èwe àwọn ọdọmọkunrin wa,jẹ́ kí wọ́n dàbí igi tí a gbìn tí ó dàgbà,kí àwọn ọdọmọbinrin wa dàbí òpó igun ilé,tí a ṣiṣẹ́ ọnà sí bíi ti ààfin ọba.

13. Kí àká wa kún fún oniruuru oúnjẹ,kí àwọn aguntan wa bí ẹgbẹẹgbẹrun,àní, ẹgbẹẹgbaarun ninu pápá oko wa.

14. Kí àwọn mààlúù wa lóyún,kí wọ́n má rọ́nú, kí wọ́n má bí òkúmọ;kí ó má sí ariwo àjálù ní ìgboro wa.

15. Ayọ̀ ń bẹ fún orílẹ̀-èdè tí ó ní irú ibukun yìí;ayọ̀ ń bẹ fún orílẹ̀-èdè tí OLUWA jẹ́ Ọlọrun wọn.