1. Nígbà tí Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti,tí àwọn ọmọ Jakọbu jáde kúrò láàrin àwọn tí ń sọ èdè àjèjì,
2. Juda di ilé mímọ́ rẹ̀,Israẹli sì di ìjọba rẹ̀.
3. Òkun rí i, ó sá,Jọdani rí i, ó pada sẹ́yìn.
4. Àwọn òkè ńláńlá ń fò bí àgbò,àwọn òkè kéékèèké ń fò bí ọmọ aguntan.
5. Kí ló dé, tí o fi sá, ìwọ òkun?Kí ló ṣẹlẹ̀ tí o fi pada sẹ́yìn, ìwọ Jọdani?
6. Ẹ̀yin òkè ńlá, kí ló dé tí ẹ fi fò bí àgbò?Ẹ̀yin òkè kéékèèké, kí ló ṣẹlẹ̀ tí ẹ fi fò bí ọmọ aguntan?
7. Wárìrì níwájú OLUWA, ìwọ ilẹ̀,wárìrì níwájú Ọlọrun Jakọbu.
8. Ẹni tí ó sọ àpáta di adágún omi,tí ó sì sọ akọ òkúta di orísun omi.