Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 45:8-17 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Aṣọ rẹ kún fún òórùn oríṣìíríṣìí turari,láti inú ààfin tí a fi eyín erin ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ni wọ́n tí ń fi ohun èlò ìkọrin olókùn dá ọ lára yá.

9. Àwọn ọmọ ọba wà lára àwọn obinrin inú àgbàlá rẹ,ayaba dúró ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ,ó fi ojúlówó wúrà ṣe ọ̀ṣọ́ sára.

10. Gbọ́, ìwọ ọmọbinrin, ronú kí o sì tẹ́tí sílẹ̀,gbàgbé àwọn eniyan rẹ ati ilé baba rẹ;

11. ẹwà rẹ yóo sì mú ọ wu ọba;òun ni oluwa rẹ, nítorí náà bu ọlá fún un.

12. Àwọn ará Tire yóo máa fi ẹ̀bùn wá ojurere rẹ,àní, àwọn eniyan tí wọ́n ní ọrọ̀ jùlọ.

13. Yóo máa wá ojurere rẹ,pẹlu oríṣìíríṣìí ọrọ̀.Ọmọ ọbabinrin fi aṣọ wúrà ṣọ̀ṣọ́ jìngbìnnì ninu yàrá rẹ̀,

14. ó wọ aṣọ aláràbarà, a mú un lọ sọ́dọ̀ ọba,pẹlu àwọn wundia ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọn ń sìn ín lọ.

15. Pẹlu ayọ̀ ati inú dídùn ni a fi ń mú wọn lọ,bí wọ́n ṣe ń wọ ààfin ọba.

16. Àwọn ọmọkunrin rẹ ni yóo rọ́pò àwọn baba rẹ;o óo fi wọ́n jọba káàkiri gbogbo ayé.

17. N óo mú kí á máa ki oríkì rẹ láti ìran dé ìran;nítorí náà àwọn eniyan yóo máa yìn ọ́ lae ati laelae.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 45