Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 44:1-12 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ọlọrun, a ti fi etí wa gbọ́,àwọn baba wa sì ti sọ fún wa,nípa àwọn ohun tí o ṣe nígbà ayé wọn,àní, ní ayé àtijọ́:

2. Ìwọ ni o fi ọwọ́ ara rẹ lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde fún wọn,tí o sì fi ẹsẹ̀ àwọn baba wa múlẹ̀;o fi ìyà jẹ àwọn orílẹ̀-èdè náà,o sì jẹ́ kí ó dára fún àwọn baba wa.

3. Nítorí pé kì í ṣe idà wọn ni wọ́n fi gba ilẹ̀ náà,kì í ṣe agbára wọn ni wọ́n fi ṣẹgun;agbára rẹ ni; àní, agbára ọwọ́ ọ̀tún rẹ,ati ojurere rẹ;nítorí pé inú rẹ dùn sí wọn.

4. Ìwọ ni Ọba mi ati Ọlọrun mi;ìwọ ni o fi àṣẹ sí i pé kí Jakọbu ó ṣẹgun.

5. Nípa agbára rẹ ni a fi bi àwọn ọ̀tá wa sẹ́yìn,orúkọ rẹ ni a fi tẹ àwọn tí ó gbógun tì wá mọ́lẹ̀.

6. Nítorí pé kì í ṣe ọrun mi ni mo gbẹ́kẹ̀lé;idà mi kò sì le gbà mí.

7. Ṣugbọn ìwọ ni o gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa,o sì dójú ti àwọn tí ó kórìíra wa.

8. Ìwọ Ọlọrun ni a fi ń yangàn nígbà gbogbo;a óo sì máa fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ títí lae.

9. Sibẹ, o ti ta wá nù o sì ti rẹ̀ wá sílẹ̀,o ò sì bá àwọn ọmọ ogun wa jáde lọ sójú ogun mọ́.

10. O ti mú kí á sá fún àwọn ọ̀tá wa lójú ogun;àwọn tí ó kórìíra wa sì fi ẹrù wa ṣe ìkógun.

11. O ti ṣe wá bí aguntan lọ́wọ́ alápatà,o sì ti fọ́n wa káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè.

12. O ti ta àwọn eniyan rẹ lọ́pọ̀,o ò sì jẹ èrè kankan lórí wọn.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 44