Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 42:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Bí ọkàn àgbọ̀nrín tií máa fà sí odò tí omi rẹ̀ tutù,bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mi ń fà sí ọ, Ọlọrun.

2. Òùngbẹ Ọlọrun ń gbẹ ọkàn mi,àní, òùngbẹ Ọlọrun alààyè.Nígbà wo ni n óo lọ, tí n óo tún bá Ọlọrun pàdé?

3. Omijé ni mo fi ń ṣe oúnjẹ jẹ tọ̀sán-tòru,nígbà tí wọn ń bi mí lemọ́lemọ́ pé,“Níbo ni Ọlọrun rẹ wà?”

4. Àwọn nǹkan wọnyi ni mò ń ranti,bí mo ti ń tú ẹ̀dùn ọkàn mi jáde:bí mo ṣe máa ń bá ogunlọ́gọ̀ eniyan rìn,tí mò ń ṣáájú wọn, bí a bá ti ń rìn lọ́wọ̀ọ̀wọ́lọ sí ilé Ọlọrun;pẹlu ìhó ayọ̀ ati orin ọpẹ́,láàrin ogunlọ́gọ̀ eniyan tí ń ṣe àjọ̀dún.

5. Ìwọ ọkàn mi, kí ló dé tí o fi rẹ̀wẹ̀sì?Kí ló dé tí ara rẹ kò fi balẹ̀ ninu mi?Gbẹ́kẹ̀ rẹ lé Ọlọrun, nítorí pé n óo tún yìn ín,olùrànlọ́wọ́ mi ati Ọlọrun mi.

6. Ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn mi,nítorí náà mo ranti rẹláti òkè Herimoni,ati láti òkè Misari, wá sí agbègbè odò Jọdani,

7. ìbànújẹ́ ń já lura wọn,ìdààmú sì ń dà gììrì,wọ́n bò mí mọ́lẹ̀ bí ìgbì omi òkun.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 42