Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 28:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ìwọ ni mo kígbe pè, OLUWA,ìwọ ni ààbò mi, má di etí sí mi.Nítorí bí o bá dákẹ́ sí min óo dàbí àwọn òkú, tí wọ́n ti lọ sinu kòtò.

2. Gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi,bí mo ti ń kígbe sí ọ pé kí o ràn mí lọ́wọ́;tí mo gbé ọwọ́ mi sókèsí ìhà ilé mímọ́ rẹ.

3. Má ṣe kó mi lọ pẹlu àwọn eniyan burúkú,pẹlu àwọn tí ń ṣe iṣẹ́ ibi,àwọn tí ń bá àwọn aládùúgbò wọnsọ ọ̀rọ̀ alaafia,ṣugbọn tí ètekéte ń bẹ ninu ọkàn wọn.

4. San án fún wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn,àní gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ burúkú wọn;san án fún wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn,fún wọn ní èrè tí ó tọ́ sí wọn.

5. Nítorí pé wọn kò ka iṣẹ́ OLUWA sí,wọn kò sì bìkítà fún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀,OLUWA yóo sọ wọ́n di ilẹ̀,kò sì ní gbé wọn dìde mọ́.

6. Ẹni ìyìn ni OLUWA!Nítorí pé ó ti gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.

7. OLUWA ni agbára ati asà mi,òun ni mo gbẹ́kẹ̀lé;ó ràn mí lọ́wọ́, ọkàn mi sì kún fún ayọ̀;mo sì fi orin ìyìn dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀.

8. OLUWA ni agbára àwọn eniyan rẹ̀;òun ni ààbò ìgbàlà fún ẹni àmì òróró rẹ̀.

9. Gba àwọn eniyan rẹ là, OLUWA,kí o sì bukun ilẹ̀ ìní rẹ.Jẹ́ olùṣọ́-aguntan wọn,kí o sì máa tọ́jú wọn títí lae.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 28