Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ọbadaya 1:8-13 BIBELI MIMỌ (BM)

8. “Ní ọjọ́ náà, ni n óo pa àwọn ọlọ́gbọ́n run ní Edomu,òye wọn yóo sì di òfo ní òkè Esau.

9. Ìwọ ìlú Temani,ìbẹ̀rùbojo yóo dé bá àwọn akọni rẹ,gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n wà ní òkè Esau ni a óo sì fi idà pa.

10. “Nítorí ìwà ìkà tí ẹ hù sí àwọn ọmọ Israẹli, arakunrin yín,ojú yóo tì yína óo sì pa yín run títí lae.

11. Ní ọjọ́ tí àwọn ọ̀tá ń kó ọrọ̀ wọn lọ,tí àwọn àjèjì wọ inú ìlú wọn,tí àwọn ọ̀tá sì ń ṣẹ́ gègé lórí Jerusalẹmu,ẹ dúró, ẹ̀ ń wò wọ́n;ẹ sì dàbí ọ̀kan ninu wọn.

12. O kì bá tí fi arakunrin rẹ ṣẹ̀sínní ọjọ́ ìpọ́njú rẹ̀;o kì bá tí jẹ́ kí inú rẹ dùn,ní ọjọ́ ìparun àwọn eniyan Juda;o kì bá tí fọ́nnu ní ọjọ́ ìbànújẹ́ wọn.

13. O kì bá tí wọ ìlú àwọn eniyan miní ọjọ́ ìpọ́njú wọn;o kì bá tí fi wọ́n ṣẹ̀sínní ọjọ́ àjálù wọn;o kì bá tí kó wọn lẹ́rùní ọjọ́ ìpọ́njú wọn.

Ka pipe ipin Ọbadaya 1