Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ọbadaya 1:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ìran tí Ọbadaya rí nìyí, OLUWA Ọlọrun sọ nípa Edomu pé:A ti gbọ́ ìròyìn láti ọ̀dọ̀ OLUWA,ó sì ti rán iranṣẹ rẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè pé:“Ẹ múra, ẹ jẹ́ kí á lọ bá Edomu jagun!”

2. Ó sọ fún Edomu pé, “Wò ó, n óo sọ ọ́ di yẹpẹrẹ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù;gbogbo ayé pátá ni yóo máa fi ọ́ ṣẹ̀sín.

3. Ìgbéraga rẹ ti tàn ọ́ jẹ,ìwọ tí ò ń gbé inú pàlàpálá òkúta,tí ibùgbé rẹ wà lórí òkè gíga,tí o sì ń wí ninu ọkàn rẹ pé, ‘Ta ni ó lè fà mí lulẹ̀?’

4. Bí o tilẹ̀ fò lọ sókè bí ẹyẹ idì,tí ó tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí ààrin àwọn ìràwọ̀,láti òkè náà ni n óo ti fà ọ́ lulẹ̀.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

5. “Bí àwọn olè bá wá bá ọ lóru,tí àwọn ọlọ́ṣà bá wá ká ọ mọ́lé lọ́gànjọ́,ṣé wọn kò ní hàn ọ́ léèmọ̀?Ṣebí ohun tí wọ́n bá fẹ́ ninu ẹrù rẹ ni wọn óo kó?Bí àwọn tí wọn ń kórè àjàrà bá wá sọ́dọ̀ rẹ,ṣebí wọn a máa fi díẹ̀ sílẹ̀?

6. Ogun ti kó Esau,gbogbo ìṣúra rẹ̀ ni wọ́n ti kó tán!

7. Gbogbo àwọn tí wọ́n bá ọ dá majẹmu ti tàn ọ́ jẹ,wọ́n sì ti lé ọ títí dé ààlà ilẹ̀ rẹ;àwọn tí ẹ jọ ń gbé ní alaafia tẹ́lẹ̀ ti di ọ̀tá rẹ;àwọn ọ̀rẹ́ tí o gbẹ́kẹ̀lé ti dẹ tàkúté sílẹ̀ dè ọ́,o kò sì mọ̀.

8. “Ní ọjọ́ náà, ni n óo pa àwọn ọlọ́gbọ́n run ní Edomu,òye wọn yóo sì di òfo ní òkè Esau.

9. Ìwọ ìlú Temani,ìbẹ̀rùbojo yóo dé bá àwọn akọni rẹ,gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n wà ní òkè Esau ni a óo sì fi idà pa.

10. “Nítorí ìwà ìkà tí ẹ hù sí àwọn ọmọ Israẹli, arakunrin yín,ojú yóo tì yína óo sì pa yín run títí lae.

11. Ní ọjọ́ tí àwọn ọ̀tá ń kó ọrọ̀ wọn lọ,tí àwọn àjèjì wọ inú ìlú wọn,tí àwọn ọ̀tá sì ń ṣẹ́ gègé lórí Jerusalẹmu,ẹ dúró, ẹ̀ ń wò wọ́n;ẹ sì dàbí ọ̀kan ninu wọn.

Ka pipe ipin Ọbadaya 1