Ìran tí Ọbadaya rí nìyí, OLUWA Ọlọrun sọ nípa Edomu pé:A ti gbọ́ ìròyìn láti ọ̀dọ̀ OLUWA,ó sì ti rán iranṣẹ rẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè pé:“Ẹ múra, ẹ jẹ́ kí á lọ bá Edomu jagun!”