Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 8:7-20 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Kí o wọ́n omi ìwẹ̀nùmọ́ sí wọn lára, kí wọ́n fi abẹ fá gbogbo irun ara wọn, kí wọ́n sì fọ aṣọ wọn, kí wọ́n sì di mímọ́.

8. Kí wọ́n mú akọ mààlúù kékeré kan ati ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò fún ẹbọ ohun jíjẹ wá. Kí wọ́n sì mú akọ mààlúù kékeré mìíràn wá, fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.

9. Lẹ́yìn náà, pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ, kí àwọn ọmọ Lefi sì dúró ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.

10. Kó àwọn ọmọ Lefi wá siwaju OLUWA, kí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sì gbé ọwọ́ lé wọn lórí,

11. kí Aaroni alufaa wá ya àwọn ọmọ Lefi sọ́tọ̀ bí ọrẹ fífì láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli, kí wọ́n lè máa ṣe iṣẹ́ ìsìn OLÚWA.

12. Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Lefi yóo gbé ọwọ́ wọn lé àwọn akọ mààlúù náà lórí. O óo fi ọ̀kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, o óo sì fi ikeji rú ẹbọ sísun sí OLÚWA, láti ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Lefi.

13. “Ya àwọn ọmọ Lefi sọ́tọ̀ fún mi gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli; wọn óo sì máa ṣe iranṣẹ fún Aaroni alufaa ati àwọn ọmọ rẹ̀.

14. Bẹ́ẹ̀ ni o óo ṣe ya àwọn ọmọ Lefi sọ́tọ̀ láàrin àwọn ọmọ Israẹli, wọn óo sì jẹ́ tèmi.

15. Lẹ́yìn tí o bá ti wẹ̀ wọ́n mọ́, tí o sì ti yà wọ́n sọ́tọ̀ bí ẹbọ fífì sí OLUWA, ni àwọn ọmọ Lefi tó lè ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ.

16. Mo ti gbà wọ́n dípò gbogbo àkọ́bí àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì di tèmi patapata.

17. Nígbà tí mo pa gbogbo àkọ́bí ní Ijipti ni mo ti ya gbogbo àkọ́bí ninu àwọn ọmọ Israẹli sọ́tọ̀ láti jẹ́ tèmi.

18. Ṣugbọn nisinsinyii, mo ti gba àwọn ọmọ Lefi dípò gbogbo àkọ́bí ninu àwọn ọmọ Israẹli.

19. Mo ti fi àwọn ọmọ Lefi fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ láti inú àwọn ọmọ Israẹli, láti máa ṣe iṣẹ́ ìsìn ninu Àgọ́ Àjọ ati láti máa ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Israẹli, kí àjàkálẹ̀ àrùn má baà bẹ́ sílẹ̀ láàrin wọn nígbà tí wọn bá súnmọ́ ibi mímọ́.”

20. Mose ati Aaroni ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sì ya àwọn ọmọ Lefi sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose pé kí wọ́n ṣe.

Ka pipe ipin Nọmba 8