Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 35:2-16 BIBELI MIMỌ (BM)

2. “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli pé ninu ilẹ̀ ìní wọn, kí wọ́n fún àwọn ọmọ Lefi ní àwọn ìlú tí wọn yóo máa gbé, kí wọ́n sì fún wọn ní ilẹ̀ pápá yíká àwọn ìlú wọnyi.

3. Àwọn ìlú náà yóo jẹ́ ti àwọn ọmọ Lefi, wọn óo máa gbébẹ̀. Ilẹ̀ tí ó yí àwọn ìlú náà ká yóo wà fún àwọn ẹran ọ̀sìn wọn ati mààlúù wọn.

4. Kí ilẹ̀ pápá tí yóo yí àwọn ìlú tí ẹ óo fún àwọn ọmọ Lefi ká jẹ́ ẹgbẹrun igbọnwọ láti ibi odi ìlú wọn siwaju.

5. Lẹ́yìn odi ìlú kọ̀ọ̀kan, kí ẹ wọn ẹgbaa igbọnwọ ní ìhà kọ̀ọ̀kan ní ìhà ìlà oòrùn, ati ìhà gúsù, ati ìhà ìwọ̀ oòrùn, ati ìhà àríwá; kí ìlú wà ní ààrin. Ilẹ̀ tí ẹ wọ̀n yìí ni yóo jẹ́ ibùjẹ fún àwọn ẹran ọ̀sìn.

6. Ninu àwọn ìlú tí ẹ óo fún àwọn ọmọ Lefi, mẹfa ninu wọn yóo jẹ́ ìlú ààbò tí ẹni tí ó bá ṣèèṣì paniyan lè sá lọ. Lẹ́yìn ìlú mẹfa yìí, ẹ óo tún fún wọn ní ìlú mejilelogoji pẹlu ilẹ̀ tí ó yí wọn ká.

7. Gbogbo ìlú tí ẹ óo fún wọn yóo jẹ́ mejidinlaadọta pẹlu ilẹ̀ pápá tí ó yí wọn ká.

8. Bí ilẹ̀ ìní olukuluku ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli bá ti tóbi tó, bẹ́ẹ̀ ni iye ìlú tí wọn yóo fi sílẹ̀ fún àwọn ọmọ Lefi yóo pọ̀ tó.”

9. OLUWA sọ fún Mose pé,

10. “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, nígbà tí wọ́n bá ré Jọdani kọjá sí ilẹ̀ Kenaani,

11. kí wọ́n yan ìlú mẹfa fún ìlú ààbò tí ẹni tí ó bá ṣèèṣì paniyan lè sá lọ.

12. Yóo jẹ́ ibi ààbò fún ẹni tí ó paniyan, bí arakunrin ẹni tí ó pa bá fẹ́ gbẹ̀san, nítorí pé ẹ kò gbọdọ̀ pa ẹni tí ó bá ṣèèṣì paniyan títí yóo fi dúró níwájú ìjọ eniyan Israẹli fún ìdájọ́.

13. Ẹ óo yan ìlú mẹfa fún èyí.

14. Mẹta ní ìhà ìlà oòrùn odò Jọdani ati mẹta ní ilẹ̀ Kenaani.

15. Wọn yóo jẹ́ ìlú ààbò fún àwọn ọmọ Israẹli tabi àwọn àlejò tí ó wà láàrin wọn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì paniyan lè sá lọ sibẹ.

16. “Ṣugbọn bí ẹnìkan bá fi ohun èlò irin lu arakunrin rẹ̀ tí ẹni náà sì kú, apànìyàn ni ẹni tí ó fi ohun èlò irin lu arakunrin rẹ̀, pípa ni wọn yóo pa òun náà.

Ka pipe ipin Nọmba 35