Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 31:14-29 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Mose bínú sí àwọn olórí ogun náà ati sí olórí ẹgbẹẹgbẹrun ati olórí ọgọọgọrun-un.

15. Ó bi wọ́n pé, “Kí ló dé tí ẹ dá àwọn obinrin wọnyi sí?

16. Ṣé ẹ ranti pé àwọn ni wọ́n tẹ̀lé ìmọ̀ràn Balaamu tí wọ́n sì mú àwọn ọmọ Israẹli ṣẹ̀ sí OLUWA ní Peori, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yìí ni àjàkálẹ̀ àrùn ṣe bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ọmọ Israẹli?

17. Nítorí náà ẹ pa gbogbo àwọn ọdọmọkunrin wọn, ati àwọn obinrin tí wọn ti mọ ọkunrin.

18. Ṣugbọn kí ẹ dá àwọn ọdọmọbinrin tí wọn kò tíì mọ ọkunrin sí, kí ẹ fi wọ́n ṣe aya fún ara yín.

19. Ǹjẹ́ nisinsinyii gbogbo àwọn tí ó bá ti paniyan tabi tí ó ti fọwọ́ kan òkú láàrin yín yóo dúró lẹ́yìn ibùdó fún ọjọ́ meje. Ní ọjọ́ kẹta ati ọjọ́ keje, àwọn ati obinrin tí wọ́n mú lójú ogun yóo ṣe ìwẹ̀nùmọ́.

20. Ẹ sì níláti fọ gbogbo aṣọ yín, ati gbogbo àwọn ohun èlò tí a fi awọ ṣe, tabi irun ewúrẹ́, tabi igi.”

21. Eleasari bá sọ fún wọn pé, “Ẹ gbọ́ ìlànà tí OLUWA ti fi lélẹ̀ láti ẹnu Mose.

22. Gbogbo wúrà, fadaka, idẹ, irin ati tánńganran ati òjé,

23. àní, gbogbo ohun tí kò bá ti lè jóná ni a óo mú la iná kọjá, kí á lè sọ wọ́n di mímọ́; a óo sì fi omi ìwẹ̀nùmọ́ fọ àwọn ohun èlò tí wọn bá lè jóná.

24. Ní ọjọ́ keje, ẹ níláti fọ aṣọ yín, kí ẹ sì di mímọ́, lẹ́yìn náà, ẹ óo pada wá sí ibùdó.”

25. OLUWA sọ fún Mose pé,

26. “Ìwọ, Eleasari ati àwọn olórí, ẹ ka gbogbo ìkógun tí ẹ kó, ati eniyan ati ẹranko.

27. Pín gbogbo ìkógun náà sí meji, kí apákan jẹ́ ti àwọn tí wọ́n lọ sójú ogun, kí apá keji sì jẹ́ ti àwọn ọmọ Israẹli yòókù.

28. Yọ apákan sílẹ̀ fún OLUWA lára ti àwọn tí wọ́n lọ sójú ogun, ninu ẹẹdẹgbẹta tí o bá kà ninu eniyan ati mààlúù ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ati ẹran ọ̀sìn, ọ̀kan jẹ́ ti OLUWA.

29. Yọ ọ́ lára ìkógun wọn kí o sì kó wọn fún Eleasari alufaa gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sí OLUWA.

Ka pipe ipin Nọmba 31