Ǹjẹ́ nisinsinyii gbogbo àwọn tí ó bá ti paniyan tabi tí ó ti fọwọ́ kan òkú láàrin yín yóo dúró lẹ́yìn ibùdó fún ọjọ́ meje. Ní ọjọ́ kẹta ati ọjọ́ keje, àwọn ati obinrin tí wọ́n mú lójú ogun yóo ṣe ìwẹ̀nùmọ́.