Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 31:1-20 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA sọ fún Mose pé,

2. “Fìyà jẹ àwọn ará Midiani fún ohun tí wọ́n ṣe sí àwọn ọmọ Israẹli. Lẹ́yìn náà, o óo kú.”

3. Mose bá sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ múra ogun kí á lè gbógun ti àwọn ará Midiani, kí á sì fìyà jẹ wọ́n fún ohun tí wọ́n ṣe sí OLUWA.

4. Ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan yóo mú ẹgbẹrun eniyan wá fún ogun náà.”

5. Nítorí náà láàrin ẹgbẹẹgbẹrun àwọn ọmọ Israẹli, ẹgbaafa (12,000) ọkunrin ni wọ́n dájọ láti lọ sójú ogun, ẹgbẹẹgbẹrun láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan.

6. Mose sì rán wọn lọ sójú ogun lábẹ́ àṣẹ Finehasi ọmọ Eleasari alufaa, pẹlu àwọn ohun èlò mímọ́ ati fèrè fún ìdágìrì lọ́wọ́ rẹ̀.

7. Wọ́n gbógun ti àwọn ará Midiani gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose, wọ́n sì pa gbogbo àwọn ọkunrin wọn.

8. Wọ́n pa àwọn ọba Midiani maraarun pẹlu. Orúkọ wọn ni: Efi, Rekemu, Suri, Huri ati Reba. Wọ́n pa Balaamu ọmọ Beori pẹlu.

9. Àwọn ọmọ Israẹli kó àwọn obinrin ati àwọn ọmọ Midiani lẹ́rú. Wọ́n kó gbogbo ẹran ọ̀sìn wọn ati gbogbo agbo ẹran wọn ati gbogbo ohun ìní wọn.

10. Wọ́n fi iná sun gbogbo ìlú wọn ati àwọn abúlé wọn,

11. wọ́n kó gbogbo ìkógun: eniyan ati ẹranko.

12. Wọ́n kó wọn wá sọ́dọ̀ Mose ati Eleasari ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu, ní òdìkejì odò Jọdani, lẹ́bàá Jẹriko.

13. Mose, Eleasari ati àwọn olórí jáde lọ pàdé àwọn ọmọ ogun náà lẹ́yìn ibùdó.

14. Mose bínú sí àwọn olórí ogun náà ati sí olórí ẹgbẹẹgbẹrun ati olórí ọgọọgọrun-un.

15. Ó bi wọ́n pé, “Kí ló dé tí ẹ dá àwọn obinrin wọnyi sí?

16. Ṣé ẹ ranti pé àwọn ni wọ́n tẹ̀lé ìmọ̀ràn Balaamu tí wọ́n sì mú àwọn ọmọ Israẹli ṣẹ̀ sí OLUWA ní Peori, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yìí ni àjàkálẹ̀ àrùn ṣe bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ọmọ Israẹli?

17. Nítorí náà ẹ pa gbogbo àwọn ọdọmọkunrin wọn, ati àwọn obinrin tí wọn ti mọ ọkunrin.

18. Ṣugbọn kí ẹ dá àwọn ọdọmọbinrin tí wọn kò tíì mọ ọkunrin sí, kí ẹ fi wọ́n ṣe aya fún ara yín.

19. Ǹjẹ́ nisinsinyii gbogbo àwọn tí ó bá ti paniyan tabi tí ó ti fọwọ́ kan òkú láàrin yín yóo dúró lẹ́yìn ibùdó fún ọjọ́ meje. Ní ọjọ́ kẹta ati ọjọ́ keje, àwọn ati obinrin tí wọ́n mú lójú ogun yóo ṣe ìwẹ̀nùmọ́.

20. Ẹ sì níláti fọ gbogbo aṣọ yín, ati gbogbo àwọn ohun èlò tí a fi awọ ṣe, tabi irun ewúrẹ́, tabi igi.”

Ka pipe ipin Nọmba 31