Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 24:8-17 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Ọlọrun kó wọn ti Ijipti wá,ó jà fún wọn gẹ́gẹ́ bí àgbáǹréré.Wọn yóo pa àwọn ọ̀tá wọn run,wọn óo wó egungun wọn, wọn óo sì fi ọfà pa wọ́n.

9. Ó dùbúlẹ̀, ó ba bíi kinniun,bí abo kinniun tí ó sùn, ta ló lè jí i dìde?Ibukun ni fún ẹni tí ó bá súre fún Israẹli,ẹni tí ó bá sì gbé Israẹli ṣépè, olúwarẹ̀ gbé!”

10. Balaki bá bínú sí Balaamu gidigidi, ó bẹ̀rẹ̀ sí fi ọwọ́ lu ọwọ́. Ó sì sọ fún Balaamu pé: “Mo pè ọ́ pé kí o wá gbé àwọn ọ̀tá mi ṣépè, ṣugbọn dípò kí o gbé wọ́n ṣépè, o súre fún wọn ní ìgbà mẹta!

11. Nítorí náà máa lọ sí ilé rẹ. Mo ti pinnu láti sọ ọ́ di eniyan pataki tẹ́lẹ̀ ni, ṣugbọn OLUWA ti dí ọ lọ́nà.”

12. Balaamu bá dáhùn pé: “Ṣebí mo ti sọ fún àwọn oníṣẹ́ tí o rán wá pé,

13. bí o tilẹ̀ fún mi ní ààfin rẹ, tí ó sì kún fún fadaka ati wúrà, sibẹsibẹ, n kò ní agbára láti ṣe ohunkohun ju ohun tí OLUWA bá sọ lọ. N kò lè dá ṣe rere tabi burúkú ní agbára mi, ohun tí OLUWA bá sọ ni n óo sọ.”

14. Balaamu tún sọ fún Balaki pé, “Èmi ń lọ sí ilé mi, ṣugbọn jẹ́ kí n kìlọ̀ fún ọ nípa ohun tí àwọn eniyan wọnyi yóo ṣe sí àwọn eniyan rẹ ní ẹ̀yìn ọ̀la.”

15. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi òwe sọ̀rọ̀, pé,“Ọ̀rọ̀ Balaamu ọmọ Beori nìyí,ọ̀rọ̀ ẹni tí ó ríran dájúdájú.

16. Ìran ẹni tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun,tí ó ní ìmọ̀ ẹni tí ó ga jùlọ,tí ó sì ń rí ìran láti ọ̀dọ̀ Olodumare.Nítòótọ́ ó ṣubú, ṣugbọn ojú rẹ̀ kò wà ní dídì.

17. Mo wo ọjọ́ iwájú rẹ,mo sì rí ẹ̀yìn ọ̀la rẹ.Ìràwọ̀ kan yóo jáde wá láàrin àwọn ọmọ Jakọbu,ọ̀pá àṣẹ yóo ti ààrin àwọn ọmọ Israẹli jáde wá;yóo run àwọn àgbààgbà Moabu,yóo sì wó àwọn ará Seti palẹ̀.

Ka pipe ipin Nọmba 24