Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 22:9-19 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Ọlọrun tọ Balaamu wá, ó bi í pé, “Àwọn ọkunrin wo ni wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ yìí?”

10. Balaamu dáhùn pé, “Balaki ọba àwọn ará Moabu ni ó rán wọn sí mi pé,

11. àwọn eniyan kan, tí wọ́n wá láti Ijipti, tẹ̀dó sórí gbogbo ilẹ̀ òun. Ó fẹ́ kí n wá bá òun ṣépè lé wọn, kí ó lè bá wọn jà, kí ó sì lè lé wọn kúrò lórí ilẹ̀ rẹ̀.”

12. Ọlọrun sọ fún Balaamu pé, “Má bá wọn lọ, má sì ṣépè lé àwọn eniyan náà nítorí ẹni ibukun ni wọ́n.”

13. Nígbà tí Balaamu jí ní òwúrọ̀, ó sọ fún àwọn oníṣẹ́ Balaki pé, “Ẹ máa lọ sí ilẹ̀ yín nítorí OLUWA ti sọ pé n kò gbọdọ̀ ba yín lọ.”

14. Nígbà náà ni wọ́n pada lọ sọ́dọ̀ Balaki, wọn sì sọ fún un wí pé Balaamu kọ̀, kò bá àwọn wá.

15. Balaki tún rán àwọn àgbààgbà mìíràn tí wọ́n pọ̀, tí wọ́n sì ṣe pataki ju àwọn ti iṣaaju lọ sí ọ̀dọ̀ Balaamu.

16. Wọ́n jíṣẹ́ fún un pé Balaki ní, “Mo bẹ̀ ọ́, má jẹ́ kí ohunkohun dí ọ lọ́wọ́ láti wá sọ́dọ̀ mi.

17. N óo sọ ọ́ di eniyan pataki, ohunkohun tí o bá sọ, n óo ṣe é. Jọ̀wọ́ wá bá mi ṣépè lé àwọn eniyan wọnyi.”

18. Balaamu dá àwọn oníṣẹ́ Balaki lóhùn pé, “Balaki ìbáà fún mi ní ààfin rẹ̀, kí ààfin náà sì kún fún fadaka ati wúrà, n kò ní lòdì sí àṣẹ OLUWA Ọlọrun mi, ninu nǹkan kékeré tabi nǹkan ńlá.

19. Ṣugbọn ẹ sùn níbí ní alẹ́ yìí, kí n lè mọ ohun tí OLUWA yóo tún bá mi sọ.”

Ka pipe ipin Nọmba 22