Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 22:29-39 BIBELI MIMỌ (BM)

29. Balaamu dáhùn pé, “Nítorí tí ò ń fi mí ṣẹ̀sín, bí ó bá jẹ́ pé idà wà lọ́wọ́ mi ni, ǹ bá ti pa ọ́.”

30. Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà dáhùn pé, “Ṣebí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ ni mí, tí o sì ti ń gùn mí láti iye ọjọ́ yìí títí di òní? Ǹjẹ́ mo hu irú ìwà báyìí sí ọ rí?”Balaamu dáhùn pé, “Rárá o.”

31. Nígbà náà ni OLUWA la Balaamu lójú láti rí angẹli tí ó dúró lójú ọ̀nà pẹlu idà lọ́wọ́ rẹ̀, Balaamu sì dojúbolẹ̀.

32. Angẹli náà bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ló dé tí o fi lu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ nígbà mẹta? Mo wá láti dínà fún ọ nítorí pé kò yẹ kí o rin ìrìn àjò yìí.

33. Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ rí mi, ó sì yà fún mi nígbà mẹta, bí bẹ́ẹ̀ bá kọ́, ǹ bá ti pa ọ́, ǹ bá sì dá òun sí.”

34. Balaamu dá angẹli náà lóhùn pé, “Mo ti dẹ́ṣẹ̀, n kò sì mọ̀ pé o dúró lójú ọ̀nà láti dínà fún mi. Ó dára, bí o kò bá fẹ́ kí n lọ, n óo pada.”

35. Angẹli OLUWA sì dáhùn pé, “Máa bá àwọn ọkunrin náà lọ, ṣugbọn ohun tí mo bá sọ fún ọ ni kí o sọ.” Balaamu sì bá wọn lọ.

36. Nígbà tí Balaki gbọ́ pé Balaamu ń bọ̀, ó jáde lọ pàdé rẹ̀ ní ìlú Moabu tí ó wà létí odò Arinoni ní ààlà ilẹ̀ Moabu.

37. Balaki wí fún un pé, “Kí ló dé tí o kò fi wá nígbà tí mo ranṣẹ sí ọ lákọ̀ọ́kọ́? Ṣé o rò pé n kò lè sọ ọ́ di ẹni pataki ni?”

38. Balaamu dáhùn pé, “Wíwá tí mo wá yìí, èmi kò ní agbára láti sọ ohunkohun bíkòṣe ohun tí OLUWA bá sọ fún mi.”

39. Balaamu bá Balaki lọ sí ìlú Kiriati-husotu.

Ka pipe ipin Nọmba 22