Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 21:27-35 BIBELI MIMỌ (BM)

27. Ìdí èyí ni àwọn akọrin òwe ṣe ń kọrin pé:“Wá sí Heṣiboni!Jẹ́ kí á tẹ ìlú ńlá Sihoni dó,kí á sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀.

28. Ní àkókò kan, láti ìlú Heṣiboni,àwọn ọmọ ogun Sihoni jáde lọ bí iná;wọ́n run ìlú Ari ní Moabu,ati àwọn oluwa ibi gíga Arinoni.

29. Ẹ̀yin ará Moabu, ẹ gbé! Ẹ di ẹni ìparun, ẹ̀yin ọmọ oriṣa Kemoṣi!Ó ti sọ àwọn ọmọkunrin yín di ẹni tí ń sálọ fún ààbò;ó sì sọ àwọn ọmọbinrin yín di ìkógunfún Sihoni ọba àwọn ará Amori.

30. Ṣugbọn nisinsinyii, a ti pa ìrandíran wọn run,láti Heṣiboni dé Diboni,láti Naṣimu dé Nofa lẹ́bàá Medeba.”

31. Àwọn ọmọ Israẹli sì tẹ̀dó sí ilẹ̀ àwọn ará Amori.

32. Mose rán eniyan lọ ṣe amí Jaseri, wọ́n sì gba àwọn ìlú agbègbè rẹ̀, wọ́n lé àwọn ará Amori tí ń gbé inú rẹ̀ kúrò.

33. Àwọn ọmọ Israẹli tún ṣí, wọ́n gba ọ̀nà Baṣani. Ogu ọba Baṣani sì bá wọn jagun ní Edirei.

34. Ṣugbọn OLUWA sọ fún Mose pé, “Má bẹ̀rù rẹ̀, mo ti fi òun ati ilẹ̀ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́. Kí o ṣe é bí o ti ṣe Sihoni ọba àwọn ará Amori tí ń gbé Heṣiboni.”

35. Àwọn ọmọ Israẹli pa Ogu ati àwọn ọmọ rẹ̀ ati gbogbo eniyan rẹ̀. Wọn kò dá ẹnìkan sí, wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn.

Ka pipe ipin Nọmba 21