Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 18:5-18 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ nìkan ni yóo máa ṣiṣẹ́ ninu ibi mímọ́ ati níbi pẹpẹ, kí ibinu mi má baà wá sórí àwọn ọmọ Israẹli mọ́.

6. Mo ti yan àwọn eniyan rẹ, àwọn ọmọ Lefi, láàrin àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn fún ọ. Wọ́n jẹ́ ẹ̀bùn fún OLUWA, wọn óo sì máa ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ.

7. Ṣugbọn ìwọ pẹlu àwọn ọmọ rẹ nìkan ni alufaa ti yóo máa ṣiṣẹ́ níbi pẹpẹ ìrúbọ ati níbi aṣọ ìbòjú. Èyí ni yóo jẹ́ iṣẹ́ yín nítorí ẹ̀bùn ni mo fi iṣẹ́ alufaa ṣe fun yín. Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ àwọn ohun mímọ́ yóo kú.”

8. OLUWA sọ fún Aaroni pé, “Mo ti fún ọ ní gbogbo ohun tí ó kù ninu àwọn ohun tí wọ́n bá fi rúbọ sí mi, ati gbogbo ohun tí àwọn ọmọ Israẹli bá yà sọ́tọ̀. Ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ ni mo fún gẹ́gẹ́ bi ìpín yín títí lae.

9. Ninu gbogbo ẹbọ mímọ́ tí a kò sun lórí pẹpẹ, ẹbọ ọrẹ, ẹbọ ohun jíjẹ, ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, tí wọn ń rú sí mi yóo jẹ́ mímọ́ jùlọ fún ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ.

10. Níbi mímọ́ ni ẹ ti gbọdọ̀ jẹ wọ́n. Àwọn ọkunrin ààrin yín nìkan ni wọ́n gbọdọ̀ jẹ wọ́n nítorí wọ́n jẹ́ ohun mímọ́ jùlọ.

11. “Bákan náà, gbogbo àwọn ọrẹ ẹbọ, ati àwọn ẹbọ fífì tí àwọn ọmọ Israẹli bá mú wá fún mi, yóo jẹ́ tiyín. Mo fún ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ lọkunrin ati lobinrin, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn títí lae. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ mímọ́ ninu wọn lè jẹ ẹ́.

12. “Mo fún ọ ní gbogbo èso àkọ́so tí àwọn ọmọ Israẹli ń mú wá fún mi lọdọọdun, ati òróró tí ó dára jùlọ, ọtí waini tí ó dára jùlọ, ati ọkà.

13. Gbogbo àwọn àkọ́so tí ó pọ́n ní ilẹ̀ náà tí wọn bá mú wá fún OLUWA yóo jẹ́ tìrẹ, ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ mímọ́ ninu ilé rẹ lè jẹ ẹ́.

14. “Gbogbo ohun tí àwọn ọmọ Israẹli bá yà sọ́tọ̀ fún mi, tìrẹ ni.

15. “Gbogbo àwọn àkọ́bí eniyan tabi ti ẹranko tí àwọn ọmọ Israẹli bá mú wá fún mi, tìrẹ ni. Ṣugbọn o óo gba owó ìràpadà dípò àkọ́bí eniyan ati ti ẹranko tí ó bá jẹ́ aláìmọ́.

16. Àwọn òbí yóo ra àwọn ọmọ wọn pada nígbà tí wọ́n bá pé ọmọ oṣù kan. Owó ìràpadà wọn jẹ́ ìwọ̀n ṣekeli marun-un. Ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́, èyí tíí ṣe ogún ìwọ̀n gera ni kí wọ́n fi wọ̀n ọ́n.

17. Ṣugbọn wọn kò ní ra àwọn àkọ́bí mààlúù, ati ti aguntan ati ti ewúrẹ́ pada, nítorí wọ́n jẹ́ mímọ́. Da ẹ̀jẹ̀ wọn sí ara pẹpẹ kí o sì fi ọ̀rá wọn rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí mi.

18. Gbogbo ẹran wọn jẹ́ tìrẹ, gẹ́gẹ́ bí àyà tí a fì níwájú pẹpẹ, ati itan ọ̀tún ṣe jẹ́ tìrẹ.

Ka pipe ipin Nọmba 18