Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 18:17-31 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Ṣugbọn wọn kò ní ra àwọn àkọ́bí mààlúù, ati ti aguntan ati ti ewúrẹ́ pada, nítorí wọ́n jẹ́ mímọ́. Da ẹ̀jẹ̀ wọn sí ara pẹpẹ kí o sì fi ọ̀rá wọn rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí mi.

18. Gbogbo ẹran wọn jẹ́ tìrẹ, gẹ́gẹ́ bí àyà tí a fì níwájú pẹpẹ, ati itan ọ̀tún ṣe jẹ́ tìrẹ.

19. “Gbogbo àwọn ẹbọ mímọ́ tí àwọn ọmọ Israẹli bá mú wá fún mi ni mo fún ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ, lọkunrin ati lobinrin, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn títí lae. Èyí jẹ́ majẹmu pataki tí mo bá ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ dá.”

20. OLUWA sọ fún Aaroni pé, “O kò gbọdọ̀ gba ohun ìní kan tí eniyan lè jogún tabi ilẹ̀ ní Israẹli. Èmi OLUWA ni yóo jẹ́ ìpín ati ìní rẹ láàrin àwọn ọmọ Israẹli.”

21. OLUWA wí pé, “Mo ti fún àwọn ọmọ Lefi ní gbogbo ìdámẹ́wàá tí àwọn ọmọ Israẹli bá mú wá fún mi gẹ́gẹ́ bí ìní wọn fún iṣẹ́ ìsìn wọn ninu Àgọ́ Àjọ.

22. Àwọn ọmọ Israẹli yòókù kò gbọdọ̀ súnmọ́ Àgọ́ Àjọ náà, kí wọn má baà dẹ́ṣẹ̀, kí wọn má baà kú.

23. Ṣugbọn àwọn ọmọ Lefi nìkan ni yóo máa ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ, wọn óo sì ru ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ìlànà ayérayé ni èyí fún arọmọdọmọ yín, wọn kò tún gbọdọ̀ ní ohun ìní kan mọ́, láàrin àwọn ọmọ Israẹli;

24. nítorí pé gbogbo ìdámẹ́wàá tí àwọn ọmọ Israẹli mú wá fún mi ni mo ti fún wọn gẹ́gẹ́ bí ìní. Ìdí sì nìyí tí mo fi sọ fun wọn pé wọn kò lè ní ohun ìní kan mọ́, láàrin àwọn ọmọ Israẹli.”

25. OLUWA rán Mose:

26. kí ó sọ fún àwọn ọmọ Lefi pé, “Nígbà tí ẹ bá gba ìdámẹ́wàá tí OLUWA ti fún yín gẹ́gẹ́ bí ìní yín, ẹ óo san ìdámẹ́wàá ninu rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fún OLUWA.

27. Ọrẹ yìí yóo dàbí ọrẹ ọkà titun, ati ọtí waini titun, tí àwọn àgbẹ̀ ń mú wá fún OLUWA.

28. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe mú ọrẹ yín wá fún OLUWA ninu ìdámẹ́wàá tí àwọn ọmọ Israẹli bá san fun yín. Ẹ óo mú ọrẹ tí ó jẹ́ ti OLUWA wá fún Aaroni alufaa.

29. Ninu èyí tí ó dára jù ninu àwọn ohun tí ẹ bá gbà ni kí ẹ ti san ìdámẹ́wàá yín.

30. Nígbà tí ẹ bá ti san ìdámẹ́wàá yín lára èyí tí ó dára jù, ìyókù jẹ́ tiyín, gẹ́gẹ́ bí àgbẹ̀ ṣe máa ń kórè oko rẹ̀ lẹ́yìn tí ó ti san ìdámẹ́wàá rẹ̀.

31. Ẹ̀yin ati ẹbí yín lè jẹ ìyókù níbikíbi tí ẹ bá fẹ́, nítorí pé ó jẹ́ èrè yín fún iṣẹ́ tí ẹ̀ ń ṣe ninu Àgọ́ Àjọ.

Ka pipe ipin Nọmba 18