Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 16:11-26 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Ṣé ẹ kò mọ̀ pé OLUWA ni ìwọ ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ ń ṣọ̀tẹ̀ sí, nígbà tí ẹ̀ ń fi ẹ̀sùn kan Aaroni? Ta ni Aaroni tí ẹ̀yin ń fi ẹ̀sùn kàn?”

12. Mose bá ranṣẹ lọ pe Datani ati Abiramu, àwọn ọmọ Eliabu, ṣugbọn wọ́n kọ̀ wọn kò wá.

13. Wọ́n ní, “O mú wa wá láti ilẹ̀ ọlọ́ràá Ijipti tí ó kún fún wàrà ati fún oyin, o fẹ́ wá pa wá sinu aṣálẹ̀ yìí, sibẹ kò tó ọ, o tún fẹ́ sọ ara rẹ di ọba lórí gbogbo wa.

14. O kò tíì kó wa dé ilẹ̀ tí ó lọ́ràá tí ó kún fún wàrà ati oyin, tabi kí o fún wa ní ọgbà àjàrà ati oko. Ṣé o fẹ́ fi júújúú bo àwọn eniyan wọnyi lójú ni, a kò ní dá ọ lóhùn.”

15. Mose bínú gidigidi, ó sì sọ fún OLUWA pé, “OLUWA, má ṣe gba ẹbọ àwọn eniyan wọnyi. N kò ṣe ibi sí ẹnikẹ́ni ninu wọn bẹ́ẹ̀ ni ń kò gba kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹnikẹ́ni wọn.”

16. Mose bá sọ fún Kora pé, “Ní ọ̀la kí ìwọ ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ wá siwaju Àgọ́ Àjọ. Aaroni pẹlu yóo wà níbẹ̀.

17. Kí olukuluku yín ati Aaroni pẹlu mú àwo turari rẹ̀, kí ẹ sì fi turari sí i láti rúbọ sí OLUWA. Gbogbo rẹ̀ yóo jẹ́ aadọtaleerugba (250) àwo turari.”

18. Olukuluku wọn sì mú àwo turari tirẹ̀, wọ́n fi ẹ̀yinná ati turari sí i, wọ́n sì dúró ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ pẹlu Mose ati Aaroni.

19. Kora kó gbogbo ìjọ eniyan náà jọ sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ láti dojú kọ Mose ati Aaroni; Ògo OLUWA sì farahàn, àwọn eniyan náà sì rí i.

20. OLUWA sì sọ fún Mose ati Aaroni pé:

21. “Ẹ bọ́ sí apá kan kí n lè rí ààyè pa àwọn eniyan náà run ní ìṣẹ́jú kan.”

22. Mose ati Aaroni bá dojúbolẹ̀, wọ́n gbadura sí OLUWA, pé, “Ọlọrun, ìwọ ni orísun ìyè, ìwọ yóo ha tìtorí ẹ̀ṣẹ̀ ẹnìkan bínú sí gbogbo ìjọ eniyan bí?”

23. OLUWA bá dá Mose lóhùn pé,

24. “Sọ fún àwọn eniyan náà kí wọ́n kúrò ní agbègbè àgọ́ àwọn Kora ati Datani ati Abiramu.”

25. Mose bá dìde pẹlu àwọn àgbààgbà Israẹli, wọ́n lọ sọ́dọ̀ Datani ati Abiramu.

26. Ó sì sọ fún àwọn eniyan pé, “Ẹ kúrò ní agbègbè àgọ́ àwọn ọkunrin burúkú wọnyi, kí ẹ má sì fọwọ́ kan nǹkankan tí ó jẹ́ tiwọn, kí ẹ má baà pín ninu ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”

Ka pipe ipin Nọmba 16