Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemaya 6:13-19 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Wọ́n bẹ̀ ẹ́ lọ́wẹ̀ kí ó lè dẹ́rù bà mí, kí n lè ṣe bí ó ti wí, kí n dẹ́ṣẹ̀, kí wọ́n lè bà mí ní orúkọ jẹ́, kí wọ́n wá kẹ́gàn mi.

14. Áà, Ọlọrun mi, ranti ohun tí Tobaya ati Sanbalati ati Noadaya, wolii obinrin, ṣe sí mi, ati àwọn wolii yòókù tí wọ́n fẹ́ máa dẹ́rù bà mí.

15. A mọ odi náà parí ní ọjọ́ kẹẹdọgbọn oṣù Eluli. Ó gbà wá ní ọjọ́ mejilelaadọta.

16. Nígbà tí àwọn ọ̀tá wa, ní gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wa ká gbọ́ nípa rẹ̀, ẹ̀rù bà wọ́n, ìtìjú sì mú wọn, nítorí wọ́n mọ̀ pé nípa ìrànlọ́wọ́ Ọlọrun ni iṣẹ́ náà fi ṣeéṣe.

17. Ati pé àwọn ọlọ́lá Juda ń kọ lẹta ranṣẹ sí Tobaya ní gbogbo àkókò yìí, Tobaya náà sì ń désì pada sí wọn.

18. Nítorí pé ọpọlọpọ àwọn ará Juda ni wọ́n ti bá a dá majẹmu, nítorí àna Ṣekanaya ọmọ Ara ni: ọmọ rẹ̀ ọkunrin, Jehohanani, ló fẹ́ ọmọbinrin Meṣulamu, ọmọ Berekaya.

19. Wọn a máa sọ gbogbo nǹkan dáradára tí ó ń ṣe lójú mi, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn a máa sọ ọ̀rọ̀ témi náà bá sọ fún un. Tobaya kò sì dẹ́kun ati máa kọ lẹta sí mi láti dẹ́rù bà mí.

Ka pipe ipin Nehemaya 6