Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemaya 6:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà tí wọ́n sọ fún Sanbalati ati Tobaya ati Geṣemu ará Arabia ati àwọn ọ̀tá wa yòókù pé a ti tún odi náà mọ, ati pé kò sí àlàfo kankan mọ́ (lóòótọ́ n kò tíì ṣe ìlẹ̀kùn sí àwọn ẹnubodè).

2. Sanbalati ati Geṣemu ranṣẹ sí mi, wọ́n ní “Wá, jẹ́ kí á pàdé ní ọ̀kan ninu àwọn ìletò tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ono.” Ṣugbọn wọ́n ti pète láti ṣe mí ní ibi.

3. Mo bá ranṣẹ pada sí wọn pé, mò ń ṣe iṣẹ́ pataki kan lọ́wọ́, kò ní jẹ́ kí n lè wá. Kò sì ní yẹ kí n dá iṣẹ́ náà dúró nítorí àtiwá rí wọn.

4. Ìgbà mẹrin ni wọ́n ranṣẹ pè mí bẹ́ẹ̀, èsì kan náà sì ni mo fún wọn ní ìgbà mẹrẹẹrin.

5. Ní ìgbà karun-un, Sanbalati rán iranṣẹ rẹ̀ kan sí mi, ó kọ lẹta ṣugbọn kò fi òǹtẹ̀ lu lẹta náà.

6. Ohun tí ó kọ sinu lẹta náà ni pé:“A fi ẹ̀sùn kàn ọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, Geṣemu náà sì jẹ́rìí sí i pé, ìwọ ati àwọn Juu ń pète láti dìtẹ̀, nítorí náà ni ẹ fi ń mọ odi yín. Ìwọ ni o sì ń gbèrò láti jọba lé wọn lórí,

Ka pipe ipin Nehemaya 6