Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemaya 5:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ọpọlọpọ àwọn eniyan náà, atọkunrin atobinrin, bẹ̀rẹ̀ sí tako àwọn Juu, arakunrin wọn.

2. Àwọn kan ń sọ pé, “Àwa, ati àwọn ọmọ wa, lọkunrin ati lobinrin, a pọ̀, ẹ jẹ́ kí á lọ wá ọkà, kí á lè máa rí nǹkan jẹ, kí á má baà kú.”

3. Àwọn mìíràn ń sọ pé, “A ti fi ilẹ̀ oko wa yáwó, ati ọgbà àjàrà wa, ati ilé wa, kí á lè rówó ra ọkà nítorí ìyàn tí ó mú yìí.”

4. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn mìíràn ń sọ pé, “A ti yá owó láti lè san owó ìṣákọ́lẹ̀ lórí ilẹ̀ oko ati ọgbà àjàrà wa.

5. Bẹ́ẹ̀ sì ni, bí àwọn arakunrin wa ti rí ni àwa náà rí, àwọn ọmọ wa kò yàtọ̀ sí tiwọn; sibẹsibẹ, à ń fi túlààsì mú àwọn ọmọ wa lọ sóko ẹrú, àwọn ọmọbinrin wa mìíràn sì ti di ẹrú pẹlu bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí nǹkan tí a lè ṣe láti dáwọ́ rẹ̀ dúró, nítorí pé ní ìkáwọ́ ẹlòmíràn ni oko wa ati ọgbà àjàrà wa wà.”

6. Inú bí mi nígbà tí mo gbọ́ igbe wọn ati ohun tí wọn ń sọ.

7. Mo rò ó lọ́kàn mi, mo sì dá àwọn ọlọ́lá ati àwọn ìjòyè lẹ́bi. Mo sọ fún wọn pé, “Ẹ̀ ń ni àwọn arakunrin yín lára.”Mo bá pe ìpàdé ńlá lé wọn lórí, mo sọ fún wọn pé,

Ka pipe ipin Nehemaya 5