Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemaya 3:21-32 BIBELI MIMỌ (BM)

21. Lẹ́yìn rẹ̀, Meremoti, ọmọ Uraya, ọmọ Hakosi, ṣe àtúnṣe apá tiwọn láti ẹnu ọ̀nà ilé Eliaṣibu títí dé òpin ilé Eliaṣibu.

22. Lẹ́yìn rẹ̀, àwọn alufaa, àwọn ará pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jọdani ṣe àtúnṣe ọ̀dọ̀ tiwọn.

23. Lẹ́yìn wọn ni Bẹnjamini ati Haṣubu ṣe àtúnṣe apá ibi tí ó kọjú sí ilé wọn. Lẹ́yìn wọn, Asaraya ọmọ Maaseaya, ọmọ Ananaya ṣe àtúnṣe ní ẹ̀gbẹ́ ilé tirẹ̀.

24. Lẹ́yìn rẹ̀, Binui, ọmọ Henadadi ṣe àtúnṣe apá ọ̀dọ̀ tirẹ̀: láti ilé Asaraya títí dé ibi Igun Odi.

25. Palali, ọmọ Usai ṣe àtúnṣe ibi tí ó kọjú sí Igun Odi ati ilé ìṣọ́, láti òkè ilé ọba níbi ọgbà àwọn olùṣọ́. Lẹ́yìn rẹ̀ ni Pedaaya, ọmọ Paroṣi,

26. ati àwọn iranṣẹ tẹmpili tí wọn ń gbé Ofeli ṣe àtúnṣe tiwọn dé ibi tí ó kọjú sí Ẹnubodè Omi, ní ìhà ìlà oòrùn ati ilé ìṣọ́ tí ó yọgun jáde títí dé ibi odi Ofeli.

27. Lẹ́yìn náà ni àwọn ará Tekoa ṣe àtúnṣe apá ibi tí ó kọjú sí ilé ìṣọ́ tí ó yọgun jáde títí dé Ofeli.

28. Àwọn alufaa ni wọ́n tún Òkè Ẹnubodè Ẹṣin ṣe, olukuluku tún ibi tí ó kọjú sí ilé rẹ̀ ṣe.

29. Lẹ́yìn wọn, Sadoku, ọmọ Imeri, ṣe àtúnṣe ibi tí ó kọjú sí ilé tirẹ̀.Lẹ́yìn rẹ̀ ni Ṣemaaya, ọmọ Ṣekanaya, olùṣọ́ ẹnu ọ̀nà ìhà ìlà oòrùn, ṣe àtúnṣe ọ̀dọ̀ tirẹ̀.

30. Lẹ́yìn rẹ̀, Hananaya, ọmọ Ṣelemaya, ati Hanuni, ọmọkunrin kẹfa ti Salafu bí ṣe àtúnṣe apá ibòmíràn.Lẹ́yìn rẹ̀ ni Meṣulamu, ọmọ Berekaya, ṣe àtúnṣe ibi tí ó kọjú sí yàrá rẹ̀.

31. Lẹ́yìn rẹ̀ Malikija, ọ̀kan ninu àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà, ṣe àtúnṣe títí dé ilé àwọn iranṣẹ tẹmpili ati ilé àwọn oníṣòwò, níbi tí ó kọjú sí Ẹnu Ọ̀nà Mifikadi, ati títí dé yàrá òkè orígun odi.

32. Àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà ati àwọn oníṣòwò sì ṣe àtúnṣe tí ó yẹ ní ààrin yàrá òkè orígun odi ati ti Ẹnu Ọ̀nà Aguntan.

Ka pipe ipin Nehemaya 3