Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemaya 3:14-20 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Malikija ọmọ Rekabu, aláṣẹ agbègbè Beti Hakikeremu, ṣe àtúnṣe Ẹnubodè Ààtàn, ó tún un kọ́, ó so àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀ ó sì ṣe àwọn ìdábùú rẹ̀.

15. Ṣalumu ọmọ Kolihose, aláṣẹ agbègbè Misipa tún Ẹnubodè Orísun ṣe, ó tún un kọ́, ó bò ó, ó sì ṣe àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀ ati ọ̀pá ìdábùú rẹ̀, ó sì tún mọ odi Adágún Ṣela ti ọgbà ọba títí kan àtẹ̀gùn tí ó wá láti ìlú Dafidi.

16. Lẹ́yìn rẹ̀, Nehemaya ọmọ Asibuki, aláṣẹ ìdajì agbègbè Betisuri ṣe àtúnṣe dé itẹ́ Dafidi, títí dé ibi adágún àtọwọ́dá ati títí dé ilé àwọn akọni.

17. Lẹ́yìn rẹ̀ ni àwọn ọmọ Lefi wọnyi ṣe àtúnṣe ọ̀dọ̀ tiwọn ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí: Rehumu ọmọ Bani ṣe àtúnṣe apá ọ̀dọ̀ tirẹ̀, lẹ́yìn rẹ̀ ni Haṣabaya, aláṣẹ ìdajì agbègbè Keila ṣe àtúnṣe agbègbè tirẹ̀.

18. Àwọn arakunrin rẹ̀ ṣe àtúnṣe agbègbè tiwọn náà: Bafai ọmọ Henadadi, aláṣẹ ìdajì agbègbè Keila ṣe ti agbègbè rẹ̀.

19. Lẹ́yìn rẹ̀ ni Eseri ọmọ Jeṣua, aláṣẹ Misipa, náà ṣe àtúnṣe apá kan lára ibi ihamọra ní ibi igun odi.

20. Lẹ́yìn rẹ̀ ni Baruku, ọmọ Sabai, ṣe àtúnṣe láti apá ibi Igun odi títí dé ẹnu ọ̀nà ilé Eliaṣibu olórí alufaa.

Ka pipe ipin Nehemaya 3