Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemaya 12:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Orúkọ àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n bá Serubabeli ọmọ Ṣealitieli ati Jeṣua dé nìwọ̀nyí: Seraaya, Jeremaya ati Ẹsira,

2. Amaraya, Maluki, ati Hatuṣi,

3. Ṣekanaya, Rehumu, ati Meremoti,

4. Ido, Ginetoi, ati Abija,

5. Mijamini, Maadaya, ati Biliga,

6. Ṣemaaya, Joiaribu ati Jedaaya,

7. Salu ati Amoku, Hilikaya, ati Jedaaya. Àwọn ni wọ́n jẹ́ olórí alufaa ati olórí àwọn arakunrin wọn ní ìgbà ayé Jeṣua.

8. Àwọn ọmọ Lefi ni: Jeṣua, Binui ati Kadimieli; Ṣerebaya, Juda, ati Matanaya, tí òun pẹlu àwọn arakunrin rẹ̀ wà nídìí ètò àwọn orin ọpẹ́.

Ka pipe ipin Nehemaya 12