Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemaya 11:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Àwọn olórí àwọn eniyan náà ń gbé Jerusalẹmu, àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù dìbò láti yan ẹnìkọ̀ọ̀kan ninu eniyan mẹ́wàá mẹ́wàá láti lọ máa gbé Jerusalẹmu, ìlú mímọ́, àwọn mẹsan-an yòókù sì ń gbé àwọn ìlú yòókù.

2. Àwọn eniyan náà súre fún àwọn tí wọ́n fa ara wọn kalẹ̀ láti lọ máa gbé Jerusalẹmu.

3. Àwọn ìjòyè ní àwọn agbègbè wọn ń gbé Jerusalẹmu, ṣugbọn ní àwọn ìlú Juda, olukuluku àwọn ọmọ Israẹli ń gbé orí ilẹ̀ rẹ̀, ní ìlú wọn, títí kan àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi, àwọn iranṣẹ tẹmpili, ati àwọn ìran iranṣẹ Solomoni.

4. Àwọn ọmọ Juda kan, ati àwọn ọmọ Bẹnjamini kan ń gbé Jerusalẹmu. Àwọn ọmọ Juda náà ni: Ataaya, ọmọ Usaya, ọmọ Sakaraya, ọmọ Amaraya, ọmọ Ṣefataya, ọmọ Mahalaleli, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Pẹrẹsi.

5. Bẹ́ẹ̀ náà ni Maaseaya, ọmọ Baruku, ọmọ Kolihose, ọmọ Hasaya, ọmọ Adaya, ọmọ Joiaribu, ọmọ Sakaraya, ọmọ ará Ṣilo.

6. Gbogbo àwọn ọmọ Peresi tí wọn ń gbé Jerusalẹmu jẹ́ akọni, wọ́n jẹ́ ọtalenirinwo ó lé mẹjọ (468).

7. Àwọn ọmọ Bẹnjamini ni: Salu ọmọ Meṣulamu, ọmọ Joẹdi, ọmọ Pedaaya, ọmọ Kolaya, ọmọ Maaseaya, ọmọ Itieli, ọmọ Jeṣaya.

8. Lẹ́yìn rẹ̀ ni Gabai ati Salai. Àpapọ̀ gbogbo àwọn ọmọ Bẹnjamini wá jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ó lé mejidinlọgbọn (928).

Ka pipe ipin Nehemaya 11