Àwọn ọmọ Juda kan, ati àwọn ọmọ Bẹnjamini kan ń gbé Jerusalẹmu. Àwọn ọmọ Juda náà ni: Ataaya, ọmọ Usaya, ọmọ Sakaraya, ọmọ Amaraya, ọmọ Ṣefataya, ọmọ Mahalaleli, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Pẹrẹsi.