orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nahumu 1 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ọ̀rọ̀ OLUWA nìyí; tí a kọ sinu ìwé ìran tí Nahumu ará Elikoṣi rí nípa ìlú Ninefe.

Ibinu OLUWA sí Ìlú Ninefe

2. OLUWA tíí jowú tíí sìí máa gbẹ̀san ni Ọlọrun.OLUWA a máa gbẹ̀san, a sì máa bínú.OLUWA a máa gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀,a sì máa fi ìrúnú rẹ̀ pamọ́ de àwọn ọ̀tá rẹ̀.

3. OLUWA kì í tètè bínú;ó lágbára lọpọlọpọ,kì í sìí dá ẹni tí ó bá jẹ̀bi láre.Ipa ọ̀nà rẹ̀ wà ninu ìjì ati ẹ̀fúùfù líle,awọsanma sì ni eruku ẹsẹ̀ rẹ̀.

4. Ó bá òkun wí, ó mú kí ó gbẹ,ó sì mú kí gbogbo odò gbẹ pẹlu;koríko ilẹ̀ Baṣani ati ti òkè Kamẹli gbẹ,òdòdó ilẹ̀ Lẹbanoni sì rẹ̀.

5. Àwọn òkè ńláńlá mì tìtì níwájú rẹ̀,àwọn òkè kéékèèké sì yọ́.Ilẹ̀ di asán níwájú rẹ̀,ayé ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀ di òfo.

6. Bí ó bá ń bínú ta ló lè dúró?Ta ló lè farada ibinu gbígbóná rẹ̀?Ìrúnú rẹ̀ a máa ru jáde bí ahọ́n iná,a sì máa fọ́ àwọn àpáta níwájú rẹ̀.

7. OLUWA ṣeun,òun ni ibi ààbò ní ọjọ́ ìdààmú;ó sì mọ àwọn tí wọn ń sálọ sọ́dọ̀ rẹ̀ fún ààbò.

8. Bí odò tí ó kún bo bèbè rẹ̀ni yóo ṣe mú ìparun bá àwọn ọ̀tá rẹ̀;yóo sì lépa àwọn ọ̀tá rẹ̀ bọ́ sí inú òkùnkùn.

9. Èrò ibi wo ni ẹ̀ ń gbà sí OLUWA?Yóo wulẹ̀ pa yín run patapata ni;kò sì sí ẹni tí OLUWA yóo gbẹ̀san lára rẹ̀ lẹ́ẹ̀kantí yóo lè ṣẹ̀ ẹ́ lẹẹkeji.

10. Wọn yóo jóná bí igbó ẹlẹ́gùn-ún tí ó dí,àní bíi koríko gbígbẹ.

11. Ṣebí ọ̀kan ninu yín ni ó ń gbìmọ̀ burúkú sí OLUWA, tí ó sì ń fúnni ní ìmọ̀ràn burúkú?

12. OLUWA wí pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará Siria lágbára, tí wọ́n sì pọ̀, a óo pa wọ́n run, wọn yóo sì parẹ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti jẹ ẹ̀yin ọmọ Juda níyà tẹ́lẹ̀, n kò ní jẹ yín níyà mọ́.

13. N óo bọ́ àjàgà Asiria kúrò lọ́rùn yín, n óo sì já ìdè yín.”

14. OLUWA ti pàṣẹ nípa Asiria, pé: “A kò ní ranti orúkọ rẹ mọ́, ìwọ ilẹ̀ Asiria, n óo run àwọn ère tí ẹ̀yin ará Asiria gbẹ́, ati àwọn tí ẹ dà, tí wọ́n wà ní ilé oriṣa rẹ, n óo gbẹ́ ibojì rẹ, nítorí ẹlẹ́gbin ni ọ́.”

15. Wo ẹsẹ̀ ẹni tí ó ń mú ìyìn rere wá lórí àwọn òkè ńláńlá, ẹni tí ń kéde alaafia! Ẹ máa ṣe àwọn àjọ̀dún yín, ẹ̀yin ará Juda, kí ẹ sì san àwọn ẹ̀jẹ́ yín, nítorí ẹni ibi kò ní gbógun tì yín mọ́, a ti pa á run patapata.