Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 7:21-36 BIBELI MIMỌ (BM)

21. Bí ẹnikẹ́ni bá fọwọ́ kan ohun àìmọ́ kan, ìbáà ṣe ohun àìmọ́ ti eniyan, tabi ti ẹranko tabi ohun ìríra kan, lẹ́yìn náà tí ó wá jẹ ninu ẹran tí a fi rú ẹbọ alaafia sí OLUWA, a óo yọ ẹni náà kúrò lára àwọn eniyan Ọlọrun.”

22. OLUWA ní kí Mose sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé,

23. “Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ọ̀rákọ́ràá, ìbáà jẹ́ ti mààlúù tabi ti aguntan tabi ti ewúrẹ́.

24. Ẹ lè lo ọ̀rá ẹran tí ó kú fúnra rẹ̀ ati ọ̀rá èyí tí ẹranko burúkú pa, fún ohun mìíràn, ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́.

25. Nítorí pé a óo yọ ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ọ̀rá ẹran tí a fi rú ẹbọ sísun sí OLUWA, kúrò lára àwọn eniyan Ọlọrun.

26. Siwaju sí i, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ ní gbogbo ibùgbé yín, bí ó ti wù kí ó rí; ìbáà jẹ́ ti ẹyẹ tabi ti ẹranko.

27. A óo yọ ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹ̀jẹ̀ kúrò lára àwọn eniyan Ọlọrun.”

28. OLUWA ní kí Mose sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé,

29. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ rú ẹbọ alaafia sí OLUWA, yóo mú ẹbọ náà wá fún OLUWA. Ninu ẹbọ alaafia rẹ̀,

30. ni yóo ti fi ọwọ́ ara rẹ̀ mú ẹbọ sísun wá fún OLUWA. Ọ̀rá ẹran náà pẹlu àyà rẹ̀ ni yóo mú wá. Alufaa yóo fi àyà ẹran náà gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú OLUWA.

31. Alufaa yóo sun ọ̀rá ẹran náà lórí pẹpẹ, ṣugbọn àyà rẹ̀ yóo jẹ́ ti Aaroni ati ti àwọn ọmọ rẹ̀.

32. Ẹ óo fún alufaa ní itan ọ̀tún rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ lára ẹbọ alaafia yín.

33. Èyíkéyìí ninu àwọn ọmọ Aaroni tí ó bá fi ẹ̀jẹ̀ ati ọ̀rá ẹran náà rúbọ ni ó ni itan ọ̀tún ẹran náà gẹ́gẹ́ bí ìpín tirẹ̀.

34. Nítorí mo ti gba àyà tí a fì ati itan tí a fi rúbọ lọ́wọ́ àwọn eniyan Israẹli lára ọrẹ ẹbọ alaafia wọn, yóo sì jẹ́ ti Aaroni, alufaa, ati àwọn ọmọ rẹ̀. Èyí ni ìpín tiwọn láti ọ̀dọ̀ àwọn eniyan Israẹli.

35. Ìpín Aaroni ni ati ti àwọn ọmọ rẹ̀, lára ẹbọ sísun tí a rú sí OLUWA, àní ẹbọ tí a yà sọ́tọ̀ fún wọn, ní ọjọ́ tí a mú wọn wá siwaju OLUWA láti máa ṣe iṣẹ́ alufaa.

36. Ní ọjọ́ tí a fi òróró yàn wọ́n, ni OLUWA ti pàṣẹ fún àwọn eniyan Israẹli láti máa fún wọn, ó jẹ́ ìpín tiwọn láti ìrandíran.”

Ka pipe ipin Lefitiku 7