Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 7:1-16 BIBELI MIMỌ (BM)

1. “Èyí ni òfin ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi.

2. Ó jẹ́ mímọ́ jùlọ; níbi tí wọ́n ti pa ẹran ẹbọ sísun ni wọ́n gbọdọ̀ ti pa ti ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, wọn yóo sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí ara pẹpẹ yípo.

3. Gbogbo ọ̀rá ara rẹ̀ ni wọ́n gbọdọ̀ fi rúbọ; ìrù tí ó lọ́ràá ati ọ̀rá tí ó bo ìfun rẹ̀,

4. àwọn kíndìnrín rẹ̀ ati ọ̀rá tí ó wà lára wọn níbi ìbàdí ati àwọn tí ó bo ẹ̀dọ̀ ni wọn óo mú pẹlu àwọn kíndìnrín náà.

5. Alufaa yóo sun wọ́n lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun fún OLUWA, ó jẹ́ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi.

6. Gbogbo ọkunrin, lára àwọn alufaa lè jẹ ninu rẹ̀, wọ́n gbọdọ̀ jẹ ẹ́ ní ibi mímọ́ nítorí pé ó jẹ́ mímọ́ jùlọ.

7. “Ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi dàbí ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, òfin kan ṣoṣo ni ó de oríṣìí ẹbọ mejeeji: òfin náà sì ni pé alufaa tí ó fi ṣe ètùtù ni ó ni ẹbọ náà.

8. Alufaa tí ó bá rú ẹbọ sísun fún eniyan ni ó ni awọ ẹran ẹbọ sísun náà.

9. Gbogbo ẹbọ ohun jíjẹ tí a yan ati gbogbo èyí tí a sè ninu apẹ tabi ninu àwo pẹrẹsẹ jẹ́ ti alufaa tí ó fi wọ́n rúbọ.

10. Gbogbo ẹbọ ohun jíjẹ tí a fi òróró pò tabi tí ó jẹ́ ìyẹ̀fun, yóo wà fún àwọn ọmọ Aaroni bákan náà.

11. “Èyí ni òfin ẹbọ alaafia, tí eniyan lè rú sí OLUWA.

12. Tí ó bá rú u fún ìdúpẹ́, yóo rú u pẹlu àkàrà tí kò ní ìwúkàrà, tí a fi òróró pò, ati àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí kò ní ìwúkàrà, tí a da òróró lé lórí, pẹlu àkàrà tí a fi ìyẹ̀fun kíkúnná ṣe, tí a fi òróró pò dáradára.

13. Ẹni tí ó bá rú ẹbọ alaafia fún ìdúpẹ́ yóo mú ẹbọ rẹ̀ wá pẹlu àkàrà tí ó ní ìwúkàrà.

14. Kí ó yọ àkàrà kọ̀ọ̀kan kúrò lára ẹbọ kọ̀ọ̀kan, kí ó fi rúbọ sí OLUWA; yóo jẹ́ ti alufaa tí ó wọ́n ẹ̀jẹ̀ ẹran ẹbọ alaafia náà sára pẹpẹ.

15. Wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ ẹran ẹbọ alaafia tí ó fi ṣe ẹbọ ọpẹ́ tán ní ọjọ́ tí ó bá rú ẹbọ náà, kò gbọdọ̀ ṣẹ́kù di ọjọ́ keji.

16. “Ṣugbọn bí ẹbọ ọrẹ rẹ̀ bá jẹ́ ti ẹ̀jẹ́ tabi ọrẹ àtinúwá, wọ́n gbọdọ̀ jẹ ẹ́ ní ọjọ́ náà, ṣugbọn bí ó bá ṣẹ́kù, wọ́n lè jẹ ẹ́ ní ọjọ́ keji;

Ka pipe ipin Lefitiku 7