Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 4:11-26 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Ṣugbọn awọ akọ mààlúù náà, ati gbogbo ẹran rẹ̀ ati orí rẹ̀ ati ẹsẹ̀ rẹ̀ ati nǹkan inú rẹ̀, ati ìgbẹ́ rẹ̀;

12. pátá ni yóo gbé jáde kúrò ninu àgọ́, lọ síbìkan tí ó bá mọ́, níbi tí wọn ń da eérú sí, yóo sì kó igi jọ, yóo dáná sun ún níbẹ̀.

13. “Tí ó bá jẹ́ pé gbogbo ìjọ eniyan Israẹli ni ó ṣèèṣì dẹ́ṣẹ̀, ṣugbọn tí ẹ̀ṣẹ̀ náà kò hàn sí ìjọ eniyan, tí wọ́n bá ṣe ọ̀kan ninu àwọn ohun gbogbo tí OLUWA ti pa láṣẹ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ ṣe, tí wọ́n sì jẹ̀bi,

14. nígbà tí wọ́n bá mọ ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá, tí wọ́n sì rí àṣìṣe wọn, gbogbo ìjọ eniyan náà yóo fi ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, wọn yóo fà á wá síbi Àgọ́ Àjọ.

15. Àwọn àgbààgbà ninu àwọn eniyan náà yóo gbé ọwọ́ wọn lé orí akọ mààlúù yìí níwájú OLUWA, wọn óo sì pa á níbẹ̀.

16. Lẹ́yìn náà ni alufaa tí a fi òróró yàn yóo mú ninu ẹ̀jẹ̀ akọ mààlúù yìí wá sinu Àgọ́ Àjọ.

17. Yóo sì ti ìka bọ inú ẹ̀jẹ̀ náà, yóo wọ́n ọn sílẹ̀ nígbà meje níwájú OLUWA, níwájú aṣọ ìbòjú tí ó wà níbi mímọ́.

18. Yóo mú ninu ẹ̀jẹ̀ tí ó kù, yóo fi sára àwọn ìwo pẹpẹ tí ó wà níwájú OLUWA ninu Àgọ́ Àjọ, yóo sì da ẹ̀jẹ̀ yòókù sílẹ̀ ní ìdí pẹpẹ ẹbọ sísun tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.

19. Yóo yọ gbogbo ọ̀rá rẹ̀ yóo sì sun ún lórí pẹpẹ.

20. Bí ó ti ṣe akọ mààlúù tí wọ́n fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ni yóo ṣe akọ mààlúù yìí pẹlu. Alufaa yóo ṣe ètùtù fún wọn, OLUWA yóo sì dáríjì wọ́n.

21. Lẹ́yìn náà, alufaa yóo gbé mààlúù yìí jáde kúrò ninu àgọ́, yóo sì sun ún bí ó ti sun mààlúù ti àkọ́kọ́; ó jẹ́ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún gbogbo ìjọ eniyan náà.

22. “Bí ìjòyè kan bá dẹ́ṣẹ̀, tí ó ṣèèṣì ṣe ọ̀kankan ninu àwọn ohun tí OLUWA Ọlọrun rẹ̀ pa láṣẹ pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe, tí ó sì jẹ̀bi,

23. nígbà tí wọ́n bá fi ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá yìí hàn án, yóo mú òbúkọ kan tí kò ní àbààwọ́n wá, yóo fi rúbọ.

24. Yóo gbé ọwọ́ lé orí òbúkọ yìí, yóo sì pa á níbi tí wọ́n ti máa ń pa ẹran ẹbọ sísun níwájú OLUWA; ó jẹ́ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.

25. Alufaa yóo ti ìka bọ inú ẹ̀jẹ̀ ẹran tí wọ́n fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ yìí yóo fi sí ara àwọn ìwo pẹpẹ ẹbọ sísun; yóo sì da ẹ̀jẹ̀ yòókù sílẹ̀ nídìí pẹpẹ.

26. Yóo sun gbogbo ọ̀rá òbúkọ náà lórí pẹpẹ, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rá ẹran tí wọ́n bá fi rú ẹbọ alaafia. Bẹ́ẹ̀ ni alufaa yóo ṣe ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, OLUWA yóo sì dáríjì í.

Ka pipe ipin Lefitiku 4