Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 4:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA ní kí Mose

2. sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, bí ẹnikẹ́ni bá ṣèèṣì ṣe ọ̀kankan ninu ohun tí OLUWA pa láṣẹ pé wọn kò gbọdọ̀ ṣe, ohun tí wọn óo ṣe nìyí:

3. “Bí ó bá jẹ́ alufaa tí a fi àmì òróró yàn ni ó ṣèèṣì dẹ́ṣẹ̀, tí ó sì kó ẹ̀bi bá àwọn eniyan, kí ó fi ọ̀dọ́ akọ mààlúù rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ níwájú OLUWA, fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá.

4. Yóo mú akọ mààlúù náà wá sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ níwájú OLUWA, yóo gbé ọwọ́ lé e lórí, yóo sì pa á níwájú OLUWA.

5. Alufaa náà yóo wá gbà ninu ẹ̀jẹ̀ akọ mààlúù náà, yóo gbé e wá sinu Àgọ́ Àjọ.

6. Yóo ti ìka rẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀ náà, yóo sì wọ́n ọn sílẹ̀ nígbà meje níwájú OLUWA, níwájú aṣọ ìkélé tí ó wà ní ibi mímọ́.

7. Lára ẹ̀jẹ̀ tí ó kù, yóo fi sára àwọn ìwo pẹpẹ turari olóòórùn dídùn tí ó wà níwájú OLUWA, ninu Àgọ́ Àjọ. Yóo sì da ẹ̀jẹ̀ akọ mààlúù yòókù sílẹ̀ nídìí pẹpẹ ẹbọ sísun tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ náà.

8. Yóo yọ́ gbogbo ọ̀rá akọ mààlúù tí ó fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ kúrò, ati gbogbo ọ̀rá tí ó bo nǹkan inú rẹ̀;

9. ati kíndìnrín rẹ̀ mejeeji, pẹlu ọ̀rá tí ó bo ibi ìbàdí ati ẹ̀dọ̀ rẹ̀

10. (gẹ́gẹ́ bí ó ti máa ń yọ wọ́n lára mààlúù tí wọn ń fi rú ẹbọ alaafia), yóo sì sun wọ́n níná lórí pẹpẹ ẹbọ sísun.

Ka pipe ipin Lefitiku 4