Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 27:6-21 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Bí ó bá jẹ́ ọmọ oṣù kan sí ọmọ ọdún marun-un, tí ó sì jẹ́ ọkunrin, yóo san ìwọ̀n ṣekeli fadaka marun-un, bí ó bá jẹ́ obinrin, yóo san ìwọ̀n ṣekeli fadaka mẹta.

7. Bí ẹni náà bá tó ẹni ọgọta ọdún tabi jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí ó bá jẹ́ ọkunrin, kí ó san ṣekeli mẹẹdogun, ṣugbọn bí ó bá jẹ́ obinrin, kí ó san Ṣekeli mẹ́wàá.

8. “Bí ẹni náà bá jẹ́ talaka tóbẹ́ẹ̀ tí kò lè san iye tí ó yẹ kí ó san, mú ẹni tí ó fi jẹ́jẹ̀ẹ́ wá sí ọ̀dọ̀ alufaa kí alufaa díye lé e gẹ́gẹ́ bí agbára ẹni tí ó jẹ́jẹ̀ẹ́ yìí.

9. “Bí ó bá jẹ́ pé ẹran ni eniyan jẹ́jẹ̀ẹ́ láti mú wá, gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sí OLUWA, gbogbo irú nǹkan bẹ́ẹ̀ tí eniyan bá fún OLUWA jẹ́ mímọ́.

10. Kò gbọdọ̀ fi ohunkohun dípò rẹ̀, tabi kí ó pààrọ̀ rẹ̀. Kò gbọdọ̀ pààrọ̀ ẹran tí kò dára sí èyí tí ó dára, tabi kí ó pààrọ̀ èyí tí ó dára sí èyí tí kò dára. Bí ó bá jẹ́ pé ó fẹ́ fi ẹran kan pààrọ̀ ẹran mìíràn, ati èyí tí wọ́n pààrọ̀, ati èyí tí wọ́n fẹ́ fi pààrọ̀ rẹ̀, wọ́n di mímọ́.

11. Bí ó bá jẹ́ ẹran tí kò mọ́ ni, tí eniyan kò lè fi rúbọ sí OLUWA, kí ẹni náà mú ẹran náà tọ alufaa wá,

12. kí alufaa wò ó bóyá ó dára tabi kò dára; iye tí alufaa bá pè é náà ni iye rẹ̀.

13. Ṣugbọn bí ẹni náà bá fẹ́ ra ẹran náà pada, yóo fi ìdámárùn-ún kún iye owó rẹ̀.

14. “Nígbà tí ẹnìkan bá ya ilé rẹ̀ sọ́tọ̀ fún OLUWA, alufaa yóo wò ó bóyá ó dára tabi kò dára; iyekíye tí alufaa bá pè é ni iye rẹ̀.

15. Bí ẹni tí ó ya ilé yìí sọ́tọ̀ fún OLUWA bá fẹ́ rà á pada, yóo san iye tí ilé náà bá tó, yóo sì tún fi ìdámárùn-ún iye owó rẹ̀ lé e. Nígbà tí ó bá san owó ilé náà pada, ilé yóo di tirẹ̀.

16. “Bí ẹnìkan bá ya apá kan ninu ilẹ̀ tí ó jogún sọ́tọ̀ fún OLUWA, ìwọ̀n èso tí eniyan bá lè rí ká lórí ilẹ̀ náà ni wọn yóo fi díye lé e. Bí a bá lè rí ìwọ̀n Homeri baali kan ká ninu rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan, iye rẹ̀ yóo jẹ́ aadọta ìwọ̀n ṣekeli fadaka.

17. Bí ó bá jẹ́ pé láti ọdún jubili ni ó ti ya ilẹ̀ náà sọ́tọ̀ fún OLUWA, iyekíye tí ilẹ̀ náà bá tó lójú yín kò gbọdọ̀ dín.

18. Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé lẹ́yìn ọdún Jubili ni ó ya ilẹ̀ rẹ̀ sọ́tọ̀ fún OLUWA, alufaa yóo ṣírò iye tí ó tó, gẹ́gẹ́ bí iye ọdún tí ó kù kí ọdún Jubili mìíràn pé bá ti pẹ́ sí, ẹ óo ṣí iye owó ọdún tí ó dínkù kúrò lára iye ilẹ̀ náà.

19. Bí ẹni tí ó ya ilẹ̀ náà sọ́tọ̀ fún OLUWA bá fẹ́ rà á pada, yóo san iye tí ó bá tó, yóo sì fi ìdámárùn-ún owó rẹ̀ lé e, ilẹ̀ náà yóo sì di tirẹ̀.

20. Ṣugbọn bí kò bá fẹ́ ra ilẹ̀ náà pada, tabi ti ó bá ti ta ilẹ̀ náà fún ẹlòmíràn, kò ní ẹ̀tọ́ láti rà á pada mọ́.

21. Ṣugbọn nígbà tí wọ́n bá jọ̀wọ́ ilẹ̀ náà ní ọdún Jubili, ó níláti jẹ́ mímọ́ fún OLUWA, gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ tí wọ́n ti fi fún OLUWA; yóo sì di ohun ìní alufaa.

Ka pipe ipin Lefitiku 27