Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 27:23-33 BIBELI MIMỌ (BM)

23. alufaa yóo ṣírò iye tí ilẹ̀ náà bá tó títí di ọdún Jubili, ẹni náà yóo sì san iye rẹ̀ ní ọjọ́ náà bí ohun ìyàsọ́tọ̀ fún OLUWA.

24. Nígbà tí ó bá di ọdún Jubili, ilẹ̀ yìí yóo pada di ti ẹni tí wọ́n rà á lọ́wọ́ rẹ̀, tí ilẹ̀ yìí jẹ́ ilẹ̀ àjogúnbá rẹ̀ láàárọ̀ ọjọ́.

25. “Ìwọ̀n ṣekeli tí wọn ń lò ninu ibi mímọ́ ni kí ẹ máa lò láti wọn ohun gbogbo: Ogún ìwọ̀n gera ni yóo jẹ́ ìwọ̀n ṣekeli kan.

26. “Ṣugbọn gbogbo ẹran tí ó bá ti jẹ́ àkọ́bí, ti OLUWA ni, ẹnikẹ́ni kò ṣẹ̀ṣẹ̀ tún ní yà á sọ́tọ̀ mọ́; kì báà jẹ́ mààlúù tabi aguntan, ti OLUWA ni.

27. Bí ó bá jẹ́ ẹran tí kò mọ́, kí ó san owó rẹ̀ pada gẹ́gẹ́ bí iye tí ẹ bá dá lé e, kí ó sì fi ìdámárùn-ún owó náà lé e. Bí ẹni tí ó ni í kò bá sì rà á pada, kí wọ́n tà á ní iyekíye tí ẹ bá dá lé e.

28. “Ṣugbọn ohunkohun tí eniyan bá ti fi fún OLUWA, kì báà jẹ́ eniyan ni, tabi ẹranko, tabi ilẹ̀ àjogúnbá rẹ̀, yóo jẹ́ títà tabi kí ó rà á pada. Ohunkohun tí a bá ti fi fún OLUWA, ó di mímọ́ jùlọ fún OLUWA.

29. Ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá yà sọ́tọ̀ pé ó gbọdọ̀ jẹ́ pípa láàrin àwọn eniyan, ẹnìkan kò gbọdọ̀ rà á pada, pípa ni wọ́n gbọdọ̀ pa á.

30. “Gbogbo ìdámẹ́wàá ilẹ̀ náà, kì báà jẹ́ ti èso ilẹ̀, tabi ti èso igi, ti OLUWA ni; mímọ́ ni fún OLUWA.

31. Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ ra ìdámẹ́wàá rẹ̀ pada, ó níláti fi ìdámárùn-ún ìdámẹ́wàá yìí lé e.

32. Ìdámẹ́wàá gbogbo agbo mààlúù, ati ti agbo aguntan jẹ́ ti OLUWA. Bí ẹran mẹ́wàá bá kọjá lábẹ́ ọ̀pá darandaran, ikẹwaa gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ fún OLUWA.

33. Darandaran náà kò gbọdọ̀ bèèrè bóyá ó dára tabi kò dára, bẹ́ẹ̀ ni kò sì gbọdọ̀ pààrọ̀ rẹ̀. Bí ó bá fẹ́ pààrọ̀ rẹ̀, ati èyí tí ó fi pààrọ̀ ati èyí tí ó pààrọ̀, mejeeji jẹ́ mímọ́ fún OLUWA, ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ rà á pada.”

Ka pipe ipin Lefitiku 27