Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 26:16-31 BIBELI MIMỌ (BM)

16. ohun tí n óo ṣe sí yín nìyí: n óo rán ìbẹ̀rù si yín lójijì, àìsàn burúkú ati ibà tí ń bani lójú jẹ́ yóo bẹ́ sílẹ̀ láàrin yín, ẹ óo sì bẹ̀rẹ̀ sí kú sára. Bí ẹ bá gbin ohun ọ̀gbìn, òfò ni yóo jásí, nítorí pé àwọn ọ̀tá yín ni yóo jẹ ẹ́.

17. N óo kẹ̀yìn sí yín, àwọn ọ̀tá yín yóo sì ṣẹgun yín. Àwọn tí ẹ kórìíra ni yóo máa jọba lórí yín, ẹ óo sì máa sá nígbà tí ẹnikẹ́ni kò le yín.

18. “Bí mo bá ṣe gbogbo èyí, sibẹ tí ẹ kò gbọ́ tèmi, n óo jẹ yín níyà ní ìlọ́po meje, fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín.

19. Pẹlu gbogbo agbára tí ẹ ní, n óo tẹ̀ yín lórí ba; òjò yóo kọ̀, kò ní rọ̀, ilẹ̀ yóo sì le bí àpáta.

20. Iṣẹ́ àṣedànù ni ẹ óo máa ṣe, nítorí pé, ilẹ̀ kò ní mú ìbísí rẹ̀ wá, àwọn igi oko kò ní so.

21. “Bí ẹ bá lòdì sí mi, tí ẹ kò sì gbọ́ tèmi, n óo jẹ yín níyà ní ìlọ́po meje, fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín.

22. N óo da àwọn ẹranko burúkú sáàrin yín, tí yóo máa gbé yín lọ́mọ lọ, wọn yóo run àwọn ẹran ọ̀sìn yín, n óo dín yín kù, tí yóo fi jẹ́ pé ilẹ̀ yín yóo di ahoro.

23. “Lẹ́yìn gbogbo èyí, bí ẹ ba kọ̀, ti ẹ kò yipada, ṣugbọn tí ẹ kẹ̀yìn sí mi,

24. èmi gan-an yóo wá kẹ̀yìn si yín, n óo sì jẹ yín níyà ní ìlọ́po meje, fún ẹ̀ṣẹ̀ yín.

25. N óo fi ogun ko yín, tí yóo gbẹ̀san nítorí majẹmu mi. Bí ẹ bá sì kó ara yín jọ sinu àwọn ìlú olódi yín, n óo rán àjàkálẹ̀ àrùn sí ààrin yín, n óo sì fi yín lé àwọn ọ̀tá yín lọ́wọ́.

26. Nígbà tí mo bá gba oúnjẹ lẹ́nu yín, obinrin mẹ́wàá ni yóo máa jókòó nídìí ẹyọ ààrò kan ṣoṣo láti ṣe burẹdi. Wíwọ̀n ni wọn yóo máa wọn oúnjẹ le yín lọ́wọ́; ẹ óo jẹ, ṣugbọn ẹ kò ní yó.

27. “Bí mo bá ṣe gbogbo èyí, tí ẹ kò sì gbọ́ tèmi, ṣugbọn tí ẹ tún kẹ̀yìn sí mi,

28. n óo fi ibinu kẹ̀yìn sí yín, n óo sì jẹ yín níyà fúnra mi, nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín.

29. Ebi yóo pa yín tóbẹ́ẹ̀ tí ẹ óo máa pa àwọn ọmọ yín jẹ.

30. N óo wó àwọn ilé ìsìn yín gbogbo tí wọ́n wà lórí òkè, n óo wó àwọn pẹpẹ turari yín lulẹ̀; n óo kó òkú yín dà sórí àwọn oriṣa yín, ọkàn mi yóo sì kórìíra yín.

31. N óo sọ àwọn ìlú yín di ahoro, àwọn ilé ìsìn yín yóo sì ṣófo, n kò ní gba ẹbọ yín mọ́.

Ka pipe ipin Lefitiku 26